Enimere Àkànbí
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Shooting Stars Sports Club, 3SC, ilẹ̀ Ìbàdàn, kùnà ní ọjọ́ ìsinmi láti gbo ewúro sí ojú orogun rẹ̀, Enyimba ti ìlú Aba, nígbà tí wọ́n jọ wọ̀dìmú ní ìlú Ìbàdàn.
Ìfigagbága náà tó wáyé ní pápá ìṣerédárayá Lékan Salami, ní ìlú Ìbàdàn, ló jẹ́ ti ọ̀sẹ̀ kẹfà, nínú líìgì àkàbà àkọ́kọ́ orílèdè Nàìjíríà, ti ọdún 2024/2025.
Yàtò sí pé Ṣúútìn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ti má ń pe, ń wá bí wọn yóó ṣe gba ẹ̀san ìyà tí Enyimba fi jẹ wọ́n ní ìlú Ìbàdàn, ní sáà tó kọjá padà, wọ́n tún ń wá bí wọn yóó ṣe mú inú àwọn alátìlẹyìn wọn dùn ní àkókò yìí.
Ẹ̀kọ ni kò tíì ṣe ojú múmu fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù ọ̀hún ní sáà yìí, pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé nínú ìfigagbága máàrún tí wọ́n ti gbá, wọ́n borí ẹyọ̀kan, ta ọ̀ọ̀mì ní ẹ̀ẹ̀méjì, nígbà tí wọ́n ti ṣubú níwájú àwọn alátakò ní ẹ̀ẹ̀méjì.
Ẹ má gbàgbé pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbábọ́ọ́lù bíi, Taofeek Málọmọ́, Christian Pyagbara tí akọ́nimọ̀ọ́gbá, Gbẹ́nga Ọ̀gúnbọ̀tẹ̀, ṣe àmúlò fi gbé 3SC dé ipò kẹrin ní orí àkàsọ̀ líìgì orílèdè Nàìjíríà, ní sáà 2023/2024, ló ti darapọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù míràn, pàápàá jù lọ, ní ilẹ̀ òkèrè.
Pitimu ni àwọn olólùfẹ́ pé sí pápá ìṣerédárayá Lékan Salami, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ní ìrètí pé 3SC yóò tún ǹǹkan ṣe, ṣùgbọ́n, kò sí ẹnì tó rí àwọ̀n ara wọn, ní ààrin ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù méjèèjì, títí àádọ́rùn-ún ìṣẹ́jú fi pé.
Ẹ jẹ́ kí n rán yín létí pé ní ilé àti òde ni Enyimba ti ba nǹkan jẹ́ mọ́ 3SC lára, ní sáà tó kọjá pẹ̀lú bí wọ́n ṣe lù wọ́n ní àmì ayò kan dondo ní ìlú Ìbàdàn àti àmì méjì sí ẹyọ̀kan ní ìlú Aba.
Tó bá di ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kẹwàá, 3SC, tó wà ní ipò kejìlá pẹ̀lú àmì mẹ́fà, yóó rin ìrìn àjò lọ sí ìlú Portharcourt láti kojú Rivers United, nígbà tí Enyimba, tó wà ní ipò kẹta pẹ̀lú àmì mẹ́tàlá, yóó jókòó sí ilé gba Niger Tornadoes ní àlejò.











Leave a Reply