Enimere Àkànbí
Olùdásílẹ̀ ìjọ Living Faith Church Worldwide, David Oyèdépò, ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ pé, bí wọ́n bá kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé pawó, kí wọ́n fún wọn ní òǹkà ojú òpó ìpè òun, pẹ̀lú àlàyé pé òun ní àṣẹ ẹ̀mí láti gbà á wọ́n sílẹ̀.
Lákòókò ìsìn tó wáyé ní àìpẹ́ yìí, ní olú ilé ìyá ìjọ rẹ̀ tó dà pè ní “Ilẹ̀ Kénáánì” ní agbègbè Ọ̀tà, ìpínlẹ̀ Ògùn, ló ti sọ̀rọ̀ yìí, tí àwọn òǹlò ojú òpó ayélujára sì gé ọ̀rọ̀ ọ̀hún jáde nínú ìwàásù rẹ̀ sí fọ́nrán tó padà de tọ́rọ́fọ́nkálé.
Òjíṣẹ́ Ọlọ́run náà fi nǹkan tó ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìṣẹ̀lẹ̀ ìyanu tó ti ṣẹlẹ̀ rí, tó ní ṣe pẹ̀lú ìjínigbé ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìjọ ọ̀hún, kín ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn.
Bàbá Oyèdépò, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe ma ń pèé, ṣàlàyé pé ó ti ṣẹlẹ̀ rí nígbà tí wọ́n jí ọ̀kan lára àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ní àjọṣe pọ̀ pẹ̀lú ìjọ òun, gbé, tí àwọn ajínigbé ọ̀hún sì bá òun sọ̀rọ̀ tààràtà lórí ẹ̀rọ ìbaraẹnisọ̀rọ̀.
Ó sì jẹ́ kó di mímọ̀ pé òun kì wọ́n nílọ̀ pẹ̀lú u àsọtẹ́lẹ̀, pé àwọn ajínigbé yóò kù ní ààrin wákàtí méjìlélógún, bí wọn kò bá fi ẹni tí wọ́n mú sílẹ̀.
Oyèdépò fi kún un pé ní ojú ẹsẹ̀ ni ibi tí àwọn ajínigbé náà wà gbọ̀n rìrì.
Nínú ìrírí míì tó lò, aṣáájú ẹ̀sìn ọ̀hún ṣàlàyé nípa bí wọ́n ṣe mú ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìjọ náà lóbìnrin, sí ìgbèkùn, tí òun sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, yóò gba òmìnira títí aago méje òwúrọ̀.
Olùdásílẹ̀ ìjọ náà sọ pé òun kò tíì pe àwọn ajínigbé rẹ̀, tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí ní fi nǹkan ṣe ara wọn, kó tó di pé wọ́n fi ọmọbìnrin ọ̀hún sílẹ̀.
Oyèdépò, wá sọ fún àwọn ọmọ ìjọ ọ̀hún pé àwọn náà ní irú àṣẹ ẹ̀mí láti ọ̀run, ọ̀hún lára, ó sì gbà wón níyànjú láti wá ara wọn rí, kí wọ́n leè má a ṣe àmúlò ẹ̀bùn náà.












Leave a Reply