SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Òfege Ní Èsì Ìdánwò Akẹ́kọ̀ọ́ Tó Gba Mẹ́rìndín-nírinwó (394) – Àjọ JAMB

the fake result
Enimere Àkànbí
Àjọ tó ń ṣètò ìdánwò aláṣẹ wọ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, JAMB, ti ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ tó di tọ́rọ́fọ́nkálé lójú òpó ayélujára pé akẹ́kọ̀ọ́ kan nípìnlẹ́ Cross River, gba mẹ́rìndín-nírinwó nínú èsì ìdánwò náà, ti ọdún yìí, gẹ́gẹ́ bíi irọ́ lásán.
Òǹlò ojú òpó ayélujára X, pẹ̀lú orúkọ @Onsogbu, ló gbé èsì ìdánwò ọ̀hún jáde pé akẹ́kọ̀ọ́ náà, tó jẹ́ obìnrin, Okon Winniefred Sampson, gba mẹ́rìndín-nírinwó, nínú irínwó.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣàtúpalẹ̀ èsì ìdánwò Okon Winniefred Sampson, ó sọ pé akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ọ̀hún gba mẹ́rìndínlọ́gọ́ọ̀rún nínú iṣẹ́ ìmọ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì, mọ́kàndínlọ́gọ́ọ̀rún nínú iṣẹ́ Biology, méjìdínlọ́gọ́ọ̀rún nínú iṣẹ́ ìmọ̀ Chemistry àti mọ́kàndínlọ́gọ́ọ̀rún nínú iṣẹ́ Physics, ó sì ṣàpèjúwe ìfakọyọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi èyí tó tayọ.
Nígbà tí Àjọ JAMB ń fèsì nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ agbẹnusọ rẹ̀, Ọ̀mọ̀wé Fabian Benjamin, fìdí RẸ̀ múlẹ̀ pé òfege ni, ó sì gba àwọn aráàlú níyànjú láti má ṣe kàákún.
Ó fi kún un pé ipò tí èsì ìdánwò tí àwọn gbé jáde wà báyìí, kìí ṣe ohun tí ó ṣe é pín kiri, ṣùgbọ́n fún akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe é nìkan láti rí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *