Enimere Àkànbí
Ọ̀kan lára àwọn tó ń fi èróńgbà hàn láti di olùdíje dupò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àsìá Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic (PDP), Olùfẹ́mi Àjàdí Ògúntóyínbòó, ti túbọ̀ fìdí ìmúratán rẹ̀ láti ró ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ lágbára gẹ́gẹ́ bíi ara akitiyan láti pèsè ọjọ́ ọ̀la tó dára fún àwọn ìran tó ń bọ̀.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé oníròyìn tó ṣe ní ọjọ́ àìkú, Àjàdí, sọ pé tí wọ́n bá leè fi ìbò gbé òun wọlé ní ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, òun yóò mójútó àwọn ẹ̀bùn tó ń bẹ ní ẹsẹ̀kùkú, bákan náà ni òun yóò pèsè àtìlẹyìn fún àwọn ọmọ aláìní.
Ó fi àkókò ọ̀hún kéde pé òun yóò ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò ìpadà sí ilé ẹ̀kọ́ tó bá di ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin, ọdún yìí, káàkiri àwọn ẹkùn tó ń bẹ nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, gẹ́gẹ́ bíi ìṣàmì ìbẹ̀rẹ̀ sáà kẹta ètò ẹ̀kọ́ ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sí ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, àfojúsùn ètò ọ̀hún ni láti ṣe àtìlẹyìn àti ìpèsè aṣọ ilé ẹ̀kọ́, ìbọ̀sẹ̀, bàtà àti àwọn èròjà ìkẹ̀kọ̀ọ́ míì, fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kò rí ọwọ́ họrí, tí àpapọ̀ wọn jẹ́ igba níye.
Àjàdí, jẹ́ kó di mímọ̀ pé ètò tí òun fẹ́ ṣe ni yóò jẹ́ ìkún lọ́wọ́ fún akitiyan ìṣàkóso Gómìnà Ṣèyí Mákindé, láti mú àdínkù bá iye àwọn ọmọ tó ti pa ẹ̀kọ́ tì nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́.
Ó ṣàlàyé síwájú pé òun àti Àjọ Catch Them Young Campaign tó fẹ́ jùmọ̀ ṣe àgbékalẹ̀ ètò ọ̀hún, yóò ríi dájú pé ó dé ọ̀dọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó nílò rẹ̀ láwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba gbogbo tó ń bẹ nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́.
Àjàdí, jẹ́ kó di mímọ̀ pé abala àkọ́kọ́ ètò ọ̀hún ni yóò wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ Òde Ajé, ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ Kúmápàyí, tó ń bẹ ní agbègbè Olódó, ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ ID, Odò-ọnà, ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ L. A Special School, tó ń bẹ ní agbègbè Gate àti ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ St. Luke’s Demonstration Basic School, Mọ̀lété, Ìbàdàn.
Àjàdí túbọ̀ ṣàlàyé pé àwọn yóò fẹ́ ètò ọ̀hún lójú dé àwọn ẹkùn míì ní àwọn ọ̀sẹ̀ tó bá tẹ́lẹ̀.












Leave a Reply