SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

ÀLÀKALẸ̀ ÈTÒ TÍ ÀWỌN OLÙDÍJE NÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC NÍ LÁTI TẸ́LẸ̀

screenshot 498

Enimere Àkànbí
Ẹgbẹ òṣèlú All Progressive Congress ti kéde ọjọ́ kẹrìndínlógún àti ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù karùn-ún, ọdún yìí gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ tí wọn yóò ètò ìdìbò abẹ́lẹ́ tí wọn yóò fi yan olùdíje fún ipò Ààrẹ àti àwọn tí yóò du ipò gómìnà ní àwọn ìpínlẹ̀, ṣáájú ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.

Akọ̀wé ìpolongo ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní àpapọ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Felix Morka, tó jẹ́ kó di mímọ̀, ṣàlàyé pé nínú àlàkalẹ̀ ètò tí akọ̀wé ìgbìmọ̀ tó ń ṣe àmójútó ètò gbogbo fún Ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún, Sulaiman Argungu, buwọ́lu, mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún náírà ni ìwé ìfi èróńgbà hàn fún ipò Ààrẹ, nígbà tí àwọn tó ń fi ìfẹ́ hàn fún ipò Gómìnà yóò san mílíọ̀nù lọ́nà àádọ́ta náírà, mílíọ̀nù lọ́nà ogún náírà ni ti àwọn tó fẹ́ lọ fún ipò aṣòfin àgbà, nígbà tí àwọn tó ń lọ fún ilé aṣòfin kékeré yóò san mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà, láti díje nínú ètò ìdìbò abẹ́lẹ́.

Ṣáájú ni Àjọ elétò ìdìbò lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, kéde ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù kínní, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ tí ètò ìdìbò sí ipò Ààrẹ àti ilé aṣòfin àpapọ̀ yóò wáyé láàrin àwọn Ẹgbẹ́ òṣèlú, nígbà tí àwọn tó ń wà ipò Gómìnà àti àwọn tó fẹ́ di ọmọ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀, yóò díje lọ́jọ́ kẹfà, oṣù kejì ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.

Àjọ INEC tún kéde pé àwọn Ẹgbẹ́ òṣèlú yóò ní àǹfààní láti yanjú gbogbo gbodónrósọ tó bá wáyé láàrin wọn lákòókò ètò ìdìbò abẹ́lẹ́, láàrin ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹrin sí ọgbọ̀njọ́ oṣù karùn-ún, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.

Àjọ INEC tún fi òǹtẹ̀ lùú pé, ìpolongo ìbò fún ipò Ààrẹ àti ilé aṣòfin àpapọ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kẹjọ, ọdún yìí, kí ti ipò Gómìnà àti ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù kẹsàn-án, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, tí a wà yìí.

Pẹ̀lú àlàkalẹ̀ ètò ẹgbẹ́ òṣèlú APC, láàrin ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kẹrin sí ọjọ́ kejì oṣù karùn-ún, ni wọn yóò fi ta ìwé ó wù mí mo fẹ́ díje, ní olú ilé ìyá Ẹgbẹ́ òṣèlú náà tó ń bẹ ní Wuse kejì, ní ìlú Abuja, tí ẹnikẹ́ni tó bá ra ìwé ọ̀hún sì gbọdọ̀ mú u kalẹ̀, kó tó di ọjọ́ kẹrin, oṣù karùn-ún.

Bákan náà ni àlàkalẹ̀ ètò ọ̀hún fi hàn pé ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù karùn-ún ni àwọn alákòóso Ẹgbẹ́ yóò ṣe àyẹ̀wò fún àwọn tó bá fi ìfẹ́ hàn fún ipò Ààrẹ, tí wọn yóò sì ṣe àyẹ̀wò fún àwọn tó fẹ́ díje fún àwọn ipò míì ní ààrin ọjọ́ kẹfà sí ìkẹjọ àti ọjọ́ kejìlá oṣù kẹtàlá, oṣù karùn-ún, ọdún yìí.
Sẹ́gun Adélakùn

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *