Enimere Àkànbí
Alákòóso ìpèsè iná ọba lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Adébáyọ̀ Adélabú, ti kọ̀wé fi ipò ọ̀hún sílẹ̀, láti rójú-ráàyè fún èróńgbà rẹ̀ láti di gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.
Nínú ìwé ọ̀hún tí ó kọ ní ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kẹrin, ọdún yìí, sí Ààrẹ Bọlá Tinúbú, ni Adélabú, ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìgbésẹ̀ òun yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní múlẹ̀ láti ọgbọ̀njọ́, oṣù kẹrin, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, láti fi fa iṣẹ́ òun lé ẹlòmíràn lọ́wọ́.
Ìwé ọ̀hún tó gba orí tábìlì akọ̀wé ìjọba oríléèdè yìí, George Akume, kọjá ni Alákòóso ìpèsè iná ọba ti fi ìbọ̀wọ́ àti ìmore hàn sí Ààrẹ Tinúbú, fún àǹfààní tó fún-un.
Adélabú, ṣàlàyé pé ìkọ̀wé fi ipò òun sílẹ̀, yóò fún òun ní àǹfààní láti rójú-ráàyè fún èróńgbà òun láti di gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.

Ó sì fi abala ìwé òfin oríléèdè Nàìjíríà tó ní ṣe pẹ̀lú ìgbésẹ̀ rẹ̀, gba nídìí.
Ìgbésẹ̀ yìí ló wáyé lẹ́yìn ìgbà tí fọ́nrán amóhùnmáwòrán kan, tó ṣe àfihàn Adélabú, tó ń sọ pé òun ti fi ara rúbọ tó, ní báyìí, òun ni ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kan.
Adélabú, ló díje du ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọdún ẹgbàá-lé-mọ́kàndínlógún, lábẹ́ àsìá Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, àti Ẹgbẹ́ òṣèlú Accord ní ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàlélógún.
Ṣùgbọ́n ó pàdánù méjèèjì sí ọwọ́ Gómìnà Ṣèyí Mákindé, ti inú Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic, PDP.
Ṣẹ́gun Adélakùn











Leave a Reply