SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Eerin(Elephant) Wọ Ààrin Ìlú, Ó Ṣekú Pa Èèyàn Kan Nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́

hgnv euxkaaxtsm

Enimere Àkànbí
Wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé èèyàn kan sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù, nígbà tí ẹlọ̀míràn nù, lẹ́yìn tí eerin ńlá kan wọ inú wá ní agbègbè Innayin, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn PUNCH rí i gbọ́ pé aago mẹ́ta ààbọ̀ ọ̀sán ọjọ́bọ̀, tí ṣe ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹrin ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni ó ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùgbé agbègbè ọ̀hún ṣe fi tó àwọn létí, pé ṣàdédé ni àwọn rí ẹranko ńlá náà.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọláyínká Àyánlàdẹ̀, ló jẹ́ kó di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde, pẹ̀lú àlàyé pé, ojú ẹsẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú Àjọṣe pọ̀ àwọn ikọ̀ aláàbò abẹ́lé àti àwọn ọdẹm

Ó ní lọ́gba tí àwọn dé ibẹ̀ ni àwọn rí òkú ẹnì kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ibrahim Tijani, ẹni ọdún márùndínláàdọ́ta, ní ìtòsí igbó, pẹ̀lú onírúurú ojú ọgbẹ́ tí ẹranko ọ̀hún ṣe síi lára.

Àyánlàdẹ̀, fi kún alaye rẹ̀ pé wọ́n ti gbé òkú náà lọ sí ẹ̀ka ìgbókùúsí ní ilé ìwòsàn ńlá ìjọba tó ń bẹ ní ìlú Ìwéré-Ilé, fún àyẹ̀wò àti láti ṣe é lọ́jọ̀.

Ó tún sọ pé ẹlòmíì tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Alhaji Muhammadu Bingin, ẹni àádọ́ta ọdún, di àwárìí lẹ́yìn tí eerin ọ̀hún ṣe ìkọlù tán, pẹ̀lú àfikún pé akitiyan ń lọ lọ́wọ́ láti ṣe àwárìí rẹ̀.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sọ pé àwọn ti rán àwọn ọlọ́pàá àti ikọ̀ aláàbò abẹ́lẹ́ lọ láti ṣe àmójútó ipò tí nǹkan wà àti dídènà ìpàdánù tó bá fẹ́ ṣúyọ.

Wọ́n sì gba àwọn olùgbé ìlú Innayin àti agbègbè rẹ̀ níyànjú láti má ṣe mikàn, kí wọ́n jìnnà sí ibi tí ìkọlù ti wáyé àti pé kí wọ́n tètè ta àwọn ikọ̀ aláàbò lólobó bí wọ́n bá kófìrí ẹranko ọ̀hún.

Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olúgbénga Abímbọ́lá, sì fi àwọn aráàlú lọ́kàn balẹ̀ nípa ààbò ẹ̀mí àti dúkìá wọn, bákan náà ló fi ẹ̀mí ìmore hàn sí wọn fún ìfọwọ́sowọpọ̀ ìgbà gbogbo wọn pẹ̀lú àwọn ikọ̀ aláàbò.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *