Enimere Àkànbí
Ní àkókò yìí tí àgbékalẹ̀ ètò ààbò ti pakasọ ní oríléèdè yìí, ni Ààrẹ Bọ́la Tinúbú, kéde pé nǹkan kó fara rọ mọ́ lẹ́ka ètò ààbò, ó sì pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ ológun àti iléeṣẹ́ ọlọ́ọ̀pá gùn lé ìgbésẹ̀ gbígba àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ síi lọ́pọ̀lọpọ̀.
Ààrẹ Tinúbú, tún sọ fún ilé aṣòfin àpapọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ àtúngbéyẹ́wò òfin tí yóò fi ààyè gba ìpínlẹ̀ yòówù tó bá ti ṣe tán láti ṣe ìdásílẹ̀ ọlọ́ọ̀pá ìpínlẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ yọ nínú àtẹ̀jáde tí Ààrẹ Tinúbú, fún ra rẹ̀ buwọ́lu, ó pàṣẹ fún ikọ̀ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, DSS, láti gbé ìgbésẹ̀ ojú ẹṣẹ̀ lórí bí wọn yóó ṣe rán àwọn aṣọ́gbó tí wọ́n ti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún, lọ sí ibi tí àwọn agbésùnmọ̀mí àti adìhámọ́ragbẹ̀mí fara sin sí làwọn igbó kìjikìji, kí wọ́n sì lé wọn lérè kúrò ní oríléèdè Nàìjíríà.
Ní ìtẹ̀sìwájú ọ̀rọ̀ Ààrẹ Tinúbú, ó sọ́ pé ikọ̀ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní àṣẹ àti àtìlẹyìn òun láti gba àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ tí yóó má a sọ́ igbó ọba, pẹ̀lú àfikún pé kò gbọdọ̀ sí ibi ìsádi kankan mọ́ fún àwọn amòkùnṣèkà àti ìránṣẹ́ ikú lórílẹ̀èdè yìí.
Bákan ni Ààrẹ pàṣẹ pé kí wọ́n lọ ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láàrin àkókò péréte nípa bí wọ́n ṣe le è péye láti dojú ìjà kọ ìṣòro ètò ààbò, fún gbogbo àwọn ọlọ́ọ̀pà tí wọ́n kó kúrò lẹ́yìn àwọn gbajúmọ̀ àti ọ̀tọ̀kùlú ìlú tí kì í ṣe aṣojú ìjọba.
Ààrẹ Tinúbú, gbóríyìn fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò fún bí wọ́n ṣe da ọwọ́ iṣẹ́ pọ̀ gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin mẹ́rinlélógún, tí àwọn agbésùnmọ̀mí jí gbé ní ìpínlẹ̀ Kebbi àti àwọn olùjọsìn méjìdínlógójì, ní ìpínlẹ̀ Kwara, sílẹ̀.
Ó sì tún yin gbogbo ìsòrí ikọ̀ ọmọ ológun láwo fún ìgboyà àti ìfararúbọ wọn.
Tinúbú, sọ pé ìṣàkóso òun yóó ṣe àtìlẹyìn fún àwọn ìpínlẹ̀ gbogbo tó ti ní àgbékalẹ̀ ikọ̀ aláàbò, láti má a fi ṣètò ààbò tó péye fún àwọn aráàlú, kúrò ní àrọ́wọ́tó àwọn agbésùnmọ̀mí, tí wọ́n múra láti ṣe àlàáfíà oríléèdè yìí ṣìbáṣìbo.
Ààrẹ gba àwọn ìpínlẹ̀ níyànjú láti tún èrò wọn pa lórí fífún àwọn èèyàn láṣẹ láti ṣe ìdásílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́, tí yóó ma ṣètò gbígbé ilé ẹ̀kọ́ kàwé fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, sí àwọn agbègbè tó jìnnà sí ìgboro, láì ní sí ètò ààbò tó péye nílẹ̀, àti wípé kí àwọn ilé ìjọsìn ọmọ lẹ́yìn Kírísítì, ẹlẹ́sìn Islam àti ti àbàláyé, má a fi tó àwọn ọlọ́ọ̀pá tàbí àwọn ikọ̀ aláàbò míràn létí, ní àwọn àkókò tí wọ́n bá fẹ́ péjọ láti jọ́sìn, pàápàá jù lọ ní àwọn agbègbè tí wọn kò ti le ran ara wọn lọ́wọ́.
Ààrẹ oríléèdè yìí, tún rọ Ẹgbẹ́ àwọn darandaran láti fi òpin sí ìlànà ìdaranjẹ̀, kí wọ́n sì kó gbogbo nǹkan dìgbòlùjá wọn tí kò bá òfin mu, lọ fún àwọn agbòfinrò, ó ṣàlàyé pé sí ṣe àmúlò ìlànà kí wọ́n má a sin màálù nínú ọgbà, ni ọ̀nà àbáyọ sí ìrẹ́sẹ̀walẹ̀ ètò iṣẹ́ àgbẹ̀ ọlọ́sìn àti ìṣọ̀kan oríléèdè Nàìjíríà, lápapọ̀.
Ó kẹ́dùn pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí gbogbo àwọn tó pàdánù olólùfẹ́ tàbí alábaṣe pọ̀ wọn nínú ìkọlù tó wáyé láìpẹ́ yìí ní ìpínlẹ̀ Kebbi, Borno, Zamfara, Niger, Yobe, àti Kwara.
Ààrẹ sì gba àwọn aráàlú níyànjú láti má ṣe sọ ìrètí nù, kí wọ́n má ṣe fi ojú sílẹ̀ fún ìbẹ̀rùbojo láti má a kó wọn ní pápá mọ́ra.









Leave a Reply