SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎Ọ̀jọ̀gbọ́n Àmúpìtàn Ṣèlérí Láti Ṣe Àgbéyẹ̀wò Àkọsílẹ̀ Ètò Ìdìbò Ọdún 2023

Images

Enimere Àkànbí
‎Alága tuntun fún àjọ elétò ìdìbò lórílẹ̀èdè Nigeria, Ọ̀jọ̀gbọ́n Joash Àmúpìtàn, ti fi èróngba hàn láti ṣe àgbéyẹ̀wò àkọsílẹ̀ àjọ náà pàápàá jù lọ gbogbo nǹkan tó ní ṣe pẹ̀lú ìgbòkègbodò ètò ìdìbò gbogbogbòò ọdún 2023.

‎Ọ̀jọ̀gbọ́n Àmúpìtàn, fi èròngbà rẹ̀ yìí hàn nígbà tí ó ń fi ìdáhùn sí ìbéèrè táwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, ń tàkòtó, síi, ní àkókò tí wọ́n ń yiri rẹ̀ wò fún ipò náà.

‎Alága tuntun ọ̀hún fún Àjọ INEC, ṣàlàyé pé àgbéyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ọ̀hún yóó ṣe ìrànwọ́ láti fi dá àwọn ìṣòro tó ń kọjú Àjọ elétò ìdìbò náà mọ́ àti láti leè mọ ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìṣòro ọ̀hún, nípa ṣíṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn tọ́rọ̀ kàn.

‎Lára àwọn àfojúsùn ti Ọ̀jọ̀gbọ́n Àmúpìtàn, kà sílẹ̀ ni idasilẹ̀ ìgbìmọ̀ tí yóó ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà àńtẹ̀lẹ́ àjùmọ̀lò lábẹ́lé nínú Àjọ INEC, àgbékalẹ̀ ìlànà ìtanilólobó, ṣiṣé ìfìdìmúlẹ̀ àkóyawọ́ àti àmúlò àwọn ìmọ̀ Ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ìrólágbára ìgbòkègbodò ètò ìdìbò àti ìlànà ètò ìdìbò.

‎Ọ̀jọ̀gbọ́n Àmúpìtàn, wá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pé ìgbẹ́kàlẹ́ àti ìlànà akọ́ṣẹ́mọsẹ́ ni yóò jẹ́ òpómúléró ìṣàkóso òun, gẹ́gẹ́ bíi alága àjọ INEC.


Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *