SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎Aṣojúṣọ̀fin Ńfẹ́ Kí Ìjọba Wá Ọ̀nà Àbáyọ Sí Ìpèsè Ìlera Àwọn Tó Ní Kòkòrò HIV/AIDS

IMG 20251017 WA0008

Enimere Àkànbí
‎Ilé Asofin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ké gbàjarè nítorí dùgbẹ̀dùgbẹ́ tí wọ́n wòye pé ó ń mì lórí ẹ̀ka ìpèsè ìlera lẹ́yìn tí àjọ elétò pàjáwìrì tí iléeṣẹ́ Ààrẹ ilẹ̀ America gbékalẹ̀ láti máa pèsè nǹkan ìdẹ̀rùn pàjáwìrì ìtọ́jú àrùn AIDS làwọn oríléèdè àgbáyé tó nílò ìrànwọ́ rẹ̀ (United States’ Presidential Emergency Plan For Aids Relief) PEPFAR, dááwọ ojúṣe rẹ̀ dúró.
‎
‎Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ yọ nínú àbá tí Asofin tó ń sójú ẹkùn ìdìbò àkọ́kọ́ àríwá Ìbàdàn, Ọnarábù Olúfúnkẹ́ Comforter-Ọlájídé, gbé wá sí iwájú ilé asofin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lákòókò ìjókòó tí igbá-kejì adarí ilé, Honourable Mohammed Fadeyi, tukọ̀ rẹ̀.
‎
‎Ọnarábù Comforter-Ọlájídé, dáàbá kí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tètè gbé ìgbésẹ̀ akin láti kọdí àwọn nǹkan burúkú tí ipò tí ọ̀rọ̀ dé dúró báyìí leè ṣókun rẹ̀ fún àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gọ́ta tó ní kòkòrò àrùn HIV àti àwọn tó ní àrùn AIDS ní ìpínlẹ̀, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àwọn irinṣẹ́ ìlera antiretroviral therapy (ART) tí àjọ náà gbékalẹ̀ làwọn iléwòsàn mọ́kànlélógún jákèjádò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ.
‎
‎PEPFAR ló jẹ́ àgbékalẹ̀ ìjọba ilẹ̀ America, láti máa pèsè ìrànwọ́ ètò ìlera fún àwọn oríléèdè àgbáyé látara bí wọ́n ṣe ń gbé owó kalẹ̀ fún ìpèsè ìlera, fífi òṣìṣẹ́ wọn ṣọwọ́ àti ìpèsè ìlera, tí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sì wà lára àwọn tó ń ṣe àmúlò àǹfààní náà.
‎
‎Ṣùgbọ́n ní báyìí, ìwé àṣẹ tí Ààrẹ Donald Trump, bu ọwọ́ lù ni pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe ìrànwọ́ náà mọ́.
‎
‎Ilé asofin ọ̀hún tó kọminú lórí ìdènà kòkòrò HIV, àrùn AIDS àti ìtọ́jú rẹ̀ tí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ń jẹ́ láti ọdún tó ti pẹ́ sẹ́yìn lára àgbékalẹ̀ PEPFAR àti bí wọ́n ṣe ti jẹ́ kí àwọn ará ìlú ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú gbékalẹ̀ ètò ìlera, wá ṣe ìkìlọ̀ pé dídá ọwọ́ iṣẹ́ àjọ náà dúró leè mú kí nǹkan pakasọ làwọn ilé ìwòsàn alábọ́dé àti ṣíṣe okùnfà kí ojúṣe àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ elétò ìlera má nítùmọ.
‎
‎Ọnarábù Comforter-Ọlájídé, nínú àbá náà pè fún kí ìgbìmọ̀ tẹ̀ẹ́kótó ilé asofin pe àpérò pẹ̀lú NEPWHAN, APYIN, ASWHAN, OYSACA, àti gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn láti ṣàgbéyẹ̀wò ibi tí ètò àmújútó ìpèsè ìlera fún àwọn tó ní kòkòrò HIV tàbí àrùn AIDS dé dúró, kí wọ́n sì tún ṣe àgbékalẹ̀ bí ètò ìlera wọn yóó ṣe máa tẹ̀ síwájú.
‎
‎

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *