Enimere Àkànbí
Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ti fi ọkàn àwọn ọmọ oríléèdè Nàìjíríà àti àwọn ẹgbẹ́ ọ̀hún balẹ̀ pé digbí ni Ẹgbẹ́ òṣèlú náà wà, pẹ̀lú ìpinnu alágbára láti gba ìṣàkóso oríléèdè yìí padà ní ọdún 2027.
Ọ̀rọ̀ akin yìí ló jẹ yọ lákòókò tí àwọn Gómìnà àti àwọn léèkàn-léèkàn nínú Ẹgbẹ́ òṣèlú náà ń fi Ẹgbẹ́ ọ̀hún sílẹ̀ lọ rèé darapọ̀ mọ́ Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, tó ń bẹ ní ìṣàkóso oríléèdè yìí àti àwọn Ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò mìíràn.
Nígba tó ń ba àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lákòókò tí ó léwájú àwọn ìgbìmọ̀ tí Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbé sílẹ̀ láti ṣíṣe lórí ètò tí wọn yóó fi túbọ̀ ró ìṣàkóso àti àgbékalẹ̀ Ẹgbẹ́ lágbára, wá ṣe àbẹ̀wò sí pápáṣeré ìdárayá Lékan Salami, tó ń bẹ ní ìlú Ìbàdàn, tí ètò ọ̀hún yíò ti wáyé ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún àti ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kọkànlá, ọdún yìí, Alága ìgbìmọ̀ náà, Umar Fintiri, fi ọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé, digbí ni Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP wà, láì náání àwọn tó lọ darapọ̀ mọ́ Ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn.
Fintiri tó jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Adamawa, fi ìtẹ̀lọ́rùn hàn sí ipò tí ìgbáradì fún ètò náà dé dúró, ó sì kan sáárá sí Gómìnà Ṣèyí Mákindé, fún àtìlẹyín àti iṣẹ́ takuntakun tó ti ṣe.

Gómìnà Fintiri tó léwájú àwọn ìgbìmọ̀ náà, tún ṣe àbẹ̀wò sí pápákọ̀ òfurufú Samuel Ládókè Akíntọ́lá, Ìbàdàn pẹ̀lú ìkúnlọ́wọ́ Gómìnà Mákindé.









Leave a Reply