Enimere Àkànbí
Ọ̀mọ̀wé Babátúndé Afees Adéníyì, tí wọ́n bí ní bíi àádọ́ta ọdún sẹ́yìn ní ìlú Ọ̀yọ́, ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìwọ̀-ọòrùn Ọ̀yọ, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn gẹ́gẹ́ bíi alága Àjọ elétò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (OYSIEC).
Ọ̀mọ̀wé Adéníyì, lẹ́yìn tí ó fi gbọ̀rọ̀ jẹkà tàn-án ní ilé ẹ̀kọ́ gíga tí wọ́n ti ń kọ́ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ àti Ìmọ̀-Ẹ̀rọ tó rọ̀ mọ, ní ìlú Igbóọrà, níbi tó ti kó ipa tó jọjú lẹ́ka olùkọ́, iṣẹ́ ìwádìí, ìdàgbàsókè ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún, ìlọsíwájú Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ àti ìgbáyégbádùn wọn, ó dára pọ̀ mọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì olùkọ́ àgbà, ti Emmanuel Aláyàndé, tó ń bẹ ní ìlú Ọ̀yọ́, gẹ́gẹ́ bíi àgbàọ̀jẹ̀ olùkọ́.
Ilé ẹ̀kọ́ náà ló wà, kí wọ́n tó yàn-án sípò alága Àjọ OYSIEC.
Ọdún 2023 ni Ọ̀mọ̀wé Adéníyì, kọ́ ẹ̀kọ́ gba ìmọ̀ òye Ọ̀mọ̀wé nípa ọrọ̀ ajé (Economics) ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì ìpínlẹ̀ Kwara, tó ń bẹ ní agbègbè Màlété, èyí tó ṣe àṣeyege rẹ̀ lẹ́yìn tí ó kọ́ ẹ̀kọ́ gba ìmọ̀ oyè àkọ́kọ́ (Master’s degrees) ní ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì Crescent tó ń bẹ ní ìlú Abẹ́òkúta, níbi tó ti gba ìmọ̀ kíkún nípa ẹ̀kọ́ ọrọ̀ ajé (Economics) àti ìmọ̀ kíkún nípa ẹ̀kọ́ ọrọ̀ ajé nínú iṣẹ́ àgbẹ̀, ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì, ìlú Ìbàdàn.
Alága tuntun fún Àjọ OYSIEC, tún jẹ́ ògúnná gbòǹgbò nínú Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀ṣíṣẹ́, kódà Ọ̀mọ̀wé Adéníyì, ti fi ìgbà kan rí jẹ́ alárinnà fún Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ làwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga gbogbonìṣe (ASUP) ẹ̀ka ilé ẹ̀kọ́ gíga tí wọ́n ti ń kọ́ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ àti Ìmọ̀-Ẹ̀rọ tó rọ̀ mọ, ní ìlú Igbóọrà, kó tó wá di Alága Ẹgbẹ́ ọ̀hún àti Akápò Ẹgbẹ́ (ASUP) ní ẹkùn Ìwọ-oòrùn oríléèdè yìí.
Bákan náà ló fi ìtàn balẹ̀ látara bí wọ́n ṣe yàn-án sípò alága àkọ́kọ́ Àgbáríjọpọ̀ Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ (JAC) láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tó sì fi àpẹrẹ aṣáájú rere hàn àti ìfìdìmúlẹ̀ ìṣọ̀kan àwọn Ẹgbẹ́ ọ̀ṣíṣẹ́.
Ọ̀mọ̀wé Adéníyì, jẹ́ ọmọ Ẹgbẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwùjọ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, bíi Ẹgbẹ́ àwọn tó ní ìmọ̀ nípa ọrọ̀ ajé lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Nigerian Economic Society (NES) àti Ẹgbẹ́ àwọn tó ní ìmọ̀ kíkún nípa ọrọ̀ ajé nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ African Association of Agricultural Economists (AAAE).
Ó ti ṣe ìgbéyàwó, tí Elédùmarè sì fi àwọn ọmọ tó yááyì tálọ́rẹ.
Ìyànsípò Ọ̀mọ̀wé Babátúndé Afees Adéníyì, gẹ́gẹ́ bíi Alága Àjọ OYSIEC ṣe àfihàn ìpéye, ìwà ọmọlúwàbí àti akitiyan rẹ̀ sí ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́, ìpè fún ìgbáyégbédùn àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ àti ìṣèjọba rere ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ní oríléèdè Nàìjíríà lápapọ̀.









Leave a Reply