SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎Ìpínlẹ̀ Èkó Ṣèlérí Àyẹ̀wò Ọpọlọ Fún Ẹnikẹ́ni Tó Bá Tàpá Sí Òfin Ojúpópó

Images 1

Enimere Àkànbí
‎Àjọ tó ń ṣe àmójútó ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Èkó, LASTMA, sọ pé àwọn yóó ṣe àfikún àyẹ̀wò ìlera ọpọlọ mọ́ ara ìjìyà tí àwọn yóó má a fi jẹ ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá tẹ̀ pé ó tàpá sí òfin ojú u pópó ní ìpínlẹ̀ náà.
‎
‎Olùdámọ̀ràn Gómìnà Babájídé Sanwó-olú, lórí ọ̀rọ̀ ìgbòkègbodò ọkọ, Ọ̀gbẹ́ni Ṣọlá Gíwá, ló sọ bẹ́ẹ̀ nígbà tó ń ka àfẹnukò ìpàdé tó wáyé níbi ayẹyẹ ọdún kẹẹ̀dọ́gbọ̀n tí wọ́n ti ṣe ìdàsílẹ̀ Àjọ LASTMA, tó wáyé ní agbègbè Victoria Island, ní ìpínlẹ̀ Èkó.
‎
‎Ọ̀gbẹ́ni Gíwá, ṣàlàyé pé àwọn ṣe àgbéjáde àfẹnukò ìpàdé ọ̀hún gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ọ̀rọ̀ kán-àn ṣe dábàá.
‎
‎Ní ìtẹ̀sìwájú ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Gíwá, ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé lára àwọn nǹkan tó ń bẹ nínú àfẹnukò náà, ni, àfikún àyẹ̀wò ìlera ọpọlọ fún àwọn tó bá tàpá sí òfin ojú u pópó, fífi ìyà tó tọ́ jẹ ẹnikẹ́ni tó bá da ojú ìjà kọ àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ LASTMA àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àtìgbàdégbà fún àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ LASTMA.
‎
‎Ọ̀gbẹ́ni Gíwá fikùn pé àwọn tún fi ẹnu kò pé àjọṣe pọ̀ tó gúnmọ́ gbọ́dọ̀ wà láàrin Àjọ LASTMA àti àwọn Àjọ tí iṣẹ́ wọn fi ara jọ ti Àjọ náà, tó fi mọ́ nínà owó sí orí iṣẹ́wádìí àti ìṣàwárí àwọn nǹkan tuntun fún Àjọ LASTMA.
‎
‎Olùdámọ̀ràn Gómìnà ọ̀hún wá gba àwọn èrò àwùjọ níyànjú láti túbọ̀ má a ṣe àtìlẹyìn fún Àjọ LASTMA, nínú ìgbìyànjú wọn láti rii dájú pé ààbò ẹ̀mí àti dúkìá àwọn olùrìnnà ń dè ní ojú pópó.
‎
‎Nínú ọ̀rọ̀ Adarí-Àgbà Ibùdó tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwùjọ (Bureau of Public Enterprises) Ọ̀gbẹ́ni Ayòdèjì Gbélẹ̀yí, gbé orí yín fún Àjọ LASTMA, fún àwọn ìlànà ìgbàlódé tó fi ń ṣe àmójútó àwọn ojú u pópó gbogbo ní ìpínlẹ̀ Èkó.
‎
‎Ọ̀gbẹ́ni Gbélẹ̀yí, tí igbá-kejì adarí ní ẹ̀ka tó ń mójútó àwọn nǹkan amáyérọrùn ní Ibùdó náà, Ọ̀gbẹ́ni Nonso Okechukwu, ṣojú, ṣàlàyé pé àwọn ìlànà ìgbàlódé náà ti jẹ́ kí ìgbòkègbodò ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó rọrùn.
‎
‎Ṣáájú ni PUNCH Metro kọ ọ́ pé Gómìnà Sanwó-olú, níbi ayẹyẹ ọdún kẹẹ̀dọ́gbọ̀n tí wọ́n ti ṣe ìdàsílẹ̀ Àjọ LASTMA, ṣèlérí pé ìjìyà tó gbọ́pan ni ìjọba òun yóó bẹ̀rẹ̀ sí ní fi jẹ ẹnikẹ́ni tó bá da ojú ìjà kọ àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ LASTMA.
‎
‎
‎

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *