SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ọ̀nà Tó Dára Jùlọ Láti Ṣe Ọdún Iléyá

IMG 20250607 WA0009

Enimere Àkànbí
“Eid-ul Adha”tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá mọ́ sí Ọdún Iléyá tàbí ayẹyẹ ìfararúbọ, jẹ́ àkókò láti ṣàgbéyẹ̀wò ore Ọlọ́run Ọba Allah lórí ayé wa.

‎Ọdún Iléyá tún jẹ́ àkókò fún àwọn Mùsùlùmí láti wo àtimáaṣebọ̀ wọn, kí wọ́n sì gbé ìwà jíjọ̀wọ́ ara wọn pátápátá fún àṣẹ Ọba Allah, wọ̀ bí ẹ̀wù, nínú ohunkóhun tí kò báà ṣẹlẹ̀ sí wọn.

‎Ní àkókò ọdún Iléyá ọ̀hún ni ẹbí, ọ̀rẹ́, alábáṣepọ̀ yóó wá láti ọ̀nà jíjìn láti péjọ pọ̀ dọ́wọ̀ọ́dùnnú, ṣe ayẹyẹ ọdún alárinrin náà tó ti wà fún ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, tí wọ́n yóó sì tún yin Ọba Allah lógo ní ọ̀nà àrà fún ọ̀kẹ́ àìmọye ìbùkún àti ore lórí ayé wọn.

‎Ìtàn fi yé ni pé, Ọdún Iléyá, ṣe àpẹẹrẹ èrè ìjólóòtọ́, jíjọ̀wọ́ ara wọn pátápátá fún àṣẹ Ọba Allah, tí ọ̀jíṣẹ́ rẹ̀, Ànábì Ibrahim, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbà pé òun ni Baba ìgbàgbọ́, èyí jẹ́ ara àwọn àmúyẹ Ànábì Ibrahim tí ó yẹ kí ọmọnìyàn má a wò kọ́ṣe, pàápàá jù lọ àwọn Mùsùlùmí òdodo.

‎Eid-ul Adha” jẹ́ ọdún tí àwọn Mùsùlùmí káàkiri àgbáyé má ń ṣe ní ọdọọdún, ní ọjọ́kejì lẹ́yìn tí àwọn tó rìnrìn àjò Hajj, bá sọ̀kalẹ̀ lórí “Òkè Arafat”. Ọ̀kan lára nǹkan gbòógì nípa Ọdún Iléyá ni ẹran àgbò pípa àti pínpín rẹ̀, èyí tó ṣe àpẹẹrẹ ìjọ́sìn àti láti ríi dájú pé inú ẹni gbogbo dùn.

‎Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ nípa ẹ̀sìn Islam ṣe sọ, ẹni tó ti wọ Iléyá àti àwọn tó ní ipá láti pa ẹran ní ọjọ́ ọdún, ni Ọlọ́run Ọba Allah ṣe ìlérí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún fún ní òdiwọ̀n iye irun tó ń bẹ lára ẹran náà, àti ìdáríjì gbogbo ẹ̀sẹ̀ tí wọ́n dá láti ọdún kan sẹ́yìn, èyí jẹ́ ìjẹ́rìí sí ẹwà tó ń bẹ nínú Ọdún Iléyá àti ẹ̀sìn Islam.

‎Ọ̀nà wo ló wá dára jù lọ tí ó yẹ kí Mùsùlùmí má a gbà ṣe ayẹyẹ Ọdún Iléyá? Kínni àwọn nǹkan tó ṣe kókó láti ṣe ní àkókò náà? Ǹjẹ́ èrè ń bẹ fún ṣíṣe ayẹyẹ náà ní ìbámu pẹ̀lú àgbékalẹ̀ ìwé mímọ́, Qu’ran? Ǹjẹ́ ìjìyà ń bẹ fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣe lòdì síi àgbékalẹ̀ náà?

‎Àkọ́kọ́ ni pé, a ṣé ní dandan fún gbogbo Mùsùlùmí láti gbaradì fún ìrun Eid, èyí tí ó gbọ́dọ̀ jẹ́ àjùmọ̀kí gẹ́gẹ́ bíi jànmọ́ọ̀ nínú mọ́ṣáláṣí tàbí àwọn ibi tí wọ́n bá yà sọ́tọ̀ fún-un. Wíwẹ ara ẹni mọ́ (Ghusl janaba) ṣáájú ìrun Eid, náà ṣe pàtàkì, tó fi mọ́ wíwọ aṣọ wa tó dára jùlọ pẹ̀lúu àwọn nǹkan olóòrùn dídùn.

IMG 20250607 WA0006 300x199

‎Ṣíṣe “Qurbani” nípa pípa àti sísun èyíkéyìí tí agbára èèyàn bá ká, yálà ẹran àgbò, àgùntàn, ewúrẹ̀, máàlù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, gẹ́gẹ́ bí ìwé Qu’ran, ṣe làákalẹ̀. Ọ̀nà mẹ́ta ni a ní láti pín ẹran ọ̀hún sí: ọ̀kan fún ara ẹni àti mọ̀lẹ́bí, èkejì fún ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀, àti ìkẹta fún àwọn aláìní.

‎Pín ẹran “Qurbani” fún àwọn aláìní, tó fi mọ́ àwọn ọmọ aláìlóòbí àti àwọn aládùúgbò.

‎Ṣe àbẹ̀wò sí ẹbí àti ọ̀rẹ́, tó fi mọ́ ìkínni (Eid Mubarak), sí wọn àti kíkópa nínú ṣíṣe ìfifúnni.

‎Fífún ara ẹni lẹ́bùn, jíjẹ oúnjẹ aládìídún, kí o sì ṣọ́ra fún ìnákúnnàá àti ìfàyègba àwọn ìwà tí kò tọ́, ríi dájú pé ò ń sọ Takbir Tashriq lẹ́yìn ìrun kọ̀ọ̀kan tí ó kìí fún gbogbo ìrun wákàtí máàrún ọjọ́ náà.

‎Ó tún ṣe kókó láti rántí ìtàn Ànábì Ibrahim, kí èèyàn ṣe àtúngbéyẹ̀wò rẹ̀, pàápàá jù lọ nípa bí ó ṣe múra tán láti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, (Ishmael) rúbọ fún Ọlọ́run Ọba Allah. A tún ní láti rántí nǹkan tó rọ̀mọ́ Eid al-Adha, gẹ́gẹ́ bíi àkókò ìrántí, ìdúpẹ́ àti ìjọ́sìn.

‎Bí àwọn Mùsùlùmí ṣe wá ń ṣe ayẹyẹ náà tí ma ń wáyé ní ọdọọdún, ó ṣe kókó láti máa tẹ́lẹ̀ ìlànà gbogbo tó rọ̀mọ́ ọ, tó fi mọ́ gbígbájúmọ́ ìwà ìkáànú, nína ọwọ́ ọọrẹ sí àwọn aláìní, kí á sì máa ṣe àmúlò ẹ̀kọ́ tí Ọdún Iléyá kọ́ wa nínú ohun gbogbo ní ẹ̀yìn ọdún, parí gbogbo rẹ̀, a ní láti ṣe Ọdún Iléyá ní ìwọ̀ntuwọ̀nsì, kí èrè rẹ̀ le ba à jẹ́ ti wa.


Adédàmọ́lá Adégòkè, ló kọọ́ láti Ìlú Mecca, Saudi Arabia

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *