SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ẹgbẹ́ NUP Ṣetán Láti Fọwọ́ Líle Mú BCOS Àti Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Ìjọba Tí Kò Tíì Máa San Àfikún Owó Ìfẹ̀yìntì Tí Mákindé Pa Láṣẹ

IMG 20250521 WA0032

Enimere Àkànbí
‎Ó ti pé oṣù márùn-ún báyìí tí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé, ti ṣe àfikún owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì láti fi mú ìdẹ̀rùn bá ètò ìgbàyégbádùn àwọn tó ti fi irun dúdú sin ìlú, tí wọ́n sì í ń fi irun funfun sinmi.

‎Kódà, ìgbésẹ̀ Gómìnà Mákindé, sọ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ di èyí tó ń san owó tó pọ̀ jùlọ fún àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì, ní orílẹ́édè Nàìjíríà.

‎Ṣùgbọ́n àwọn iléeṣẹ́ kan kò tẹ́lẹ̀ àṣẹ Gómìnà Mákindé, tí kò kí ń fi ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ àti òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣeré.

‎Èyí ló mú ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, NUP, ẹ̀ka ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, pe àkíyèsí Gómìnà Mákindé, síi pé àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó jẹ́ ti ìjọba ìpínlẹ̀ àti iléeṣẹ́ móhùnmáwòrán Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, BCOS, kò tẹ́lẹ̀ àṣẹ tó pa, pé kí àlèékún bá owóoṣù àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì.

‎Wọ́n sì ní kí Gómìnà Mákindé, gbé ìgbésẹ̀ akin nípa rẹ̀ àti ìwádìí lórí nǹkan tó mú kí àwọn aláṣẹ àwọn iléeṣẹ́ tí ọ̀rọ̀ kán-àn, tako àṣẹ Gómìnà.

‎Níbi ìpàdé tí àwọn aṣáájú Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe pẹ̀lú àwọn àwọn tó fẹ̀yìntì ní Iléeṣẹ́ BCOS, Ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe tìlú Ìbàdàn (The Polytechnic, NUP, Ìbàdàn), Ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì ìmọ̀ ẹ̀rọ ti Ládòkè Akíntọ́lá (LAUTECH) àti ẹ̀ka ìkẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn rẹ̀, Ilé ẹ̀kọ́ni gíga Fáṣítì olùkọ́ àgbà ti Emmanuel Aláyàndé tó ń bẹ nílùú Ọ̀yọ́, Ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe tó ń bẹ nílùú Ṣakí (Òkè-Ògùn Polytechnic, NUP), Ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe tó ń bẹ nílùú Èrúwà (The Polytechnic NUP, Èrúwà) àti ilé ẹ̀kọ́ni olùkọ́ àgbà, tó ń bẹ nílùú Làǹlátẹ̀ (Ọ̀yọ State College of Education, NUP).

IMG 20250521 WA0036 300x225

‎Nínúu gbàngàn tó ń bẹ ní ilé àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tó kalẹ̀ sí agbègbè Àgbárìgọ-Onírèké, Ìbàdàn, ni ìpàdé náà ti wáyé.

‎Nígbà tí Akọ̀wé àgbà ẹgbẹ́ NUP, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Comrade Olúṣẹ́gun Àbátàn, ń sọ̀rọ̀, ó ṣàlàyé kíkún nípa akitiyan àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ àti èsì tí wọ́n rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ gbogbo tí ọ̀rọ̀ kán-àn.

‎Gẹ́gẹ́ bí Comrade Àbátàn, ṣe jẹ́ kó di mímọ pẹ̀lú ẹ̀dà ìwé tí àwọn iléeṣẹ́ ọ̀hún fi fèsì fún wọn, àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ gíga ọ̀hún tó jẹ́ ti ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi àáké kọ́rí pé bí àwọn kò bá rí ìwé àṣẹ gbà láti ọ̀dọ̀ Gómìnà Mákindé, àwọn kò ní san àlèékún owó oṣù fún àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì.

IMG 20250521 WA0048 169x300 IMG 20250521 WA0047 169x300

‎Nígbàtí ìgbìmọ̀ aláṣẹ iléeṣẹ́ BCOS ní ti wọn, ṣe ìlérí pé àwọn yóó bẹ̀rẹ̀ sí ní san-án owó náà ní ìparí oṣù kẹrin ọdún yìí, ṣùgbọ́n títí di àkókò yìí wọn kò san owó ti àtẹ̀yìnwá dépò pé wọn yóó mú ìlérí tuntun ṣẹ.

‎Alága ẹgbẹ́ àwọn tó fẹ̀yìntì ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó ń bẹ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Comrade Sólómọ́nì Ọládiípọ̀ àti ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ alága ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Comrade Waheed Ọlọ́jẹ̀dé, tó bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, sọ pé àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ tí ọ̀rọ̀ kán-àn kò bá ṣe nǹkan tí àwọn ń fẹ́, àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì náà yóó ṣe ohun tí wọn kò lérò.

‎Ṣáájú, nínú ọ̀rọ̀ Alága ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Comrade James Ọ̀ṣúntádé, fi àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì tí ọ̀rọ̀ kán-àn lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ yóó dá ẹ̀rín pa ẹ̀kẹ́ wọn, gẹ́gẹ́ bíi ti àtẹ̀yìnwá.

IMG 20250521 WA0040 300x225

‎Àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì, wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Gómìnà Mákindé, láti bá wọn sọ́ níbi tí àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ ọ̀hún ti ń gbọ́, bíbẹ́ẹ̀kọ́ bí Gómìnà bá rí àwọn àti àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì tí ọ̀rọ̀ kán-àn, tí wọ́n ń ṣe ìfẹ̀hùnnúhàn, kó mọ̀ pé, àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ náà ló ya ọmọ ọsàn, tó ń kó póńpó bá ìyá rẹ̀.

‎Bákan náà ni wọ́n ní kí Gómìnà Mákindé, da àwọn tó fẹ̀yìntì ní iléeṣẹ́ móhùnmáwòrán Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, BCOS, pọ̀ mọ́ ọmọ tọ́, nípa sísọ wọ́n di ojúlówó ọmọ Àjọ tó ń rí sọ́rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.


Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *