SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ọdún Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n Ìṣèjọba Àwarawa Ní Nàìjíríà, IPAC Fún Mọ́gàjì Ọlágúnjú Ní Àmì Ẹ̀yẹ

IMG 20241226 WA0033

Enimere Àkànbí
Ìgbìmọ̀ àgbàríjọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ní orílèdè Nàìjíríà, (IPAC) ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ti fi àmì ẹ̀yẹ ta alága Àjọ tó ń ṣe ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (OYSIEC) Mọ́gàjì Isiaka Abíọ́lá Ọlágúnjú, ní ọrẹ, gẹ́gẹ́ bíi ògúnnágbòhùngbò nínú ìfìdímúlẹ̀ ìṣèjọba àwarawa.

Nibi ètò ìdànilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ kan tí ìgbìmọ̀ IPAC gbé kalẹ̀ láti fi ṣe àmì ayẹyẹ ọdún kẹẹ̀dọ́gbọ̀n tí ìṣèjọba àwarawa tí fìdí kalẹ̀ ní orílèdè Nàìjíríà, láìsí ohunkóhun tó síi nídìí, ni wọ́n ti fún àgbáọ̀jẹ́ amọ̀fin náà ní àmì ẹ̀yẹ fún ipa tó ń kó nínú ètò ìṣèjọba àti òṣèlú.

Níbi ètò ọ̀hún tó wáyé nínú gbọ̀ngàn àpérò àgbáyé, tó ń bẹ nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì ìlú Ìbàdàn, ni wọ́n ti fún àwọn èèyàn tó ní orúkọ ní àwùjọ, bíi, alákòóso fún ọ̀rọ̀ ìpèsè iná ọba ní orílèdè Nàìjíríà, Olóyè Adébáyọ̀ Adélabú, Alága ìjọba ìbílẹ̀ àríwá Ìbàdàn, Ọnarébù Abdulrahmon Adépọ̀jù, Ọnarébù obìnrin, Olóyè Adébùkọ̀lá Àjàjá, Ọ̀jọ̀gbọ́n Akin Ọ̀ṣun àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ, náà ní àmì ẹ̀yẹ.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àkòrí ètò ọ̀hún, Alága Ìgbìmọ̀ àgbàríjọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ní orílèdè Nàìjíríà, (IPAC) ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀túnba Adégbénrò Fágbèmí, fi ìgbàgbọ́ hàn pé ní àìpẹ́, orílèdè Nàìjíríà yóò mọ ìṣèjọba àwarawa dunjúndujún àti wípé yóò mú àtúnṣe bá gbogbo àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tó ń jẹ yọ.

IMG 20241226 WA0035 300x199

Ọ̀túnba Fágbèmí, ṣe àlàyé síwájú pé ogun abẹ́nú nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kọ̀ọ̀kan ló bí àìsíṣọ̀kan àti rúgúdù tó ń wáyé ní agbo òsèlú, pẹ̀lú àfikún pé ìgbìmò IPAC ti kó ipa tó jọjú nínú bí àìgbọ́raẹniyé yóó ṣe dínkù ní àárín àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú, pàápàá jù lọ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Nínú ọ̀rọ̀ Alága Àjọ tó ń ṣe ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (OYSIEC) Mọ́gàjì Isiaka Abíọ́lá Ọlágúnjú, ní kété tí ó gba àmì ẹ̀yẹ ọ̀hún tán, fi ẹ̀mí ìmọ̀ore hàn sí àwọn aṣíwájú IPAC, ó tún fi àkókò ọ̀hún gbé orí yìn fún ìgbìmọ̀ IPAC lórí àjọṣepọ tó gúnmọ́ àti àyìlẹyìn tí wọ́n ṣe fún àjọ OYSIEC ní àkókò ètò ìdìbò alága ìjọba ìbílẹ̀ tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ó sì rọ̀ wọ́n láti má ṣe pẹ̀yìndà láti má a ṣe ojúṣe wọn.

IMG 20241226 WA0034 199x300

Mọ́gàjì Ọlágúnjú, fi ọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé ojú ọ̀nà ìṣelógo ìjọba àwarawa ni orílèdè Nàìjíríà ń tọ̀, pẹ̀lú ìtọ́kasí pé ó tó nǹkan ayẹyẹ pẹ̀lú bí orílèdè Nàìjíríà ṣe ti ń jẹ ìgbádùn ìjọba àwarawa fún ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, láìní àbùlà.

Àgbàọ̀jẹ̀ amọ̀fin ọ̀uń, wá gba àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú gbogbo tó ń bẹ ní orílèdè Nàìjíríà níyànjú láti má a rí dájú pé wọ́n ń tẹ́lẹ̀ àlàkálẹ̀ òfin, kí wọ́n sì máa ṣe ojúṣe wọn bó ṣe tọ́ àti bí ó ṣe yẹ.

Nígbà tó ń gbé ìdànilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ kalẹ̀, Máyẹ̀ Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, àgbàoyè Lékan Àlàbí, pè fún àgbékalẹ̀ àyíká tí yóò máa ṣe ìgbé lárugẹ ètò ìdìbò tó mányánlórí, láìní sí kọ́núhunkọ́họ kankan ní orílèdè Nàìjíríà.

Olóyè Àlàbí tẹ ẹnu mọ́ ọ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ní láti máa gbé ìyàtọ̀ ẹ̀sìn àti àṣà tó ń bẹ ní ààrin wọn tì sí ẹ̀gbẹ́ kan, ní àkókò ètò ìdìbò, kí wọ́n sì má a panupọ̀ yan ẹni tó tọ́ sípò.

Nínú àlàyé olùdánilẹ́kọ̀ọ́ kejì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Gòkè Lálùdé, láti ẹ̀ka tí wọ́n ti ń kọ́ nípa òṣèlú àti ìṣàkóso ìlú, ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì Fountain, nìlú Òṣogbo, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, sọ pé ètò ìdìbò tó mányánlórí le ṣééṣe láìsí ìlọ́wọ́síi ẹ̀rọ ayélujára tí wọ́n fi ń ṣe ètò ìdìbò ní ayé òde òní.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Lálùdé, wá dà àbá ìjìyà tó ní àpẹẹrẹ fún àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ fún ìwà àjẹbánu àti àgbékalẹ̀ ètò tí yóó ṣe àlàkálẹ̀ ojúṣe ẹni kọ̀ọ̀kan tó di ipò ìlú mú.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *