SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Adìhàmọ́ragbẹ̀mi Gbẹ̀mí Ọba Agamo Nípìnlẹ́ Òǹdó

Ondo Monarch

Enimere Àkànbí
Ikọ̀ kan tí àwọn èèyàn gbàgbọ́ pé adìhàmọ́ragbẹ̀mi ni wọ́n ti ṣekú pa aṣáájú àwùjọ Agamo, ní ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Àkúrẹ́, ti ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọba Kẹ́hìndé Jacob Faledon, lákòókò tí wọ́n gbìyànjú láti jíi gbé lọ.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló ti mú jìnnìjìnnì bá àwọn ará agbègbè ọ̀hún lórí ipò tí ètò ààbò agbègbè náà wàá.

Ó dé etígbọ̀ àwọn olùgbé agbègbè náà ní ọjọ́bọ̀, pé àwọn ikọ̀ ọ̀hún yabo ààfin ọba ọ̀hún ní alẹ́ ọjọ́rú pẹ̀lú èròńgbà láti jíi gbé lọ, ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ wọn yọrí sí ikú Ọba Faledon, tí ó bá wọn ṣagídí.

Ìtòsí ààfin rẹ̀ ni wọ́n ti rí òkú rẹ̀ pẹ̀lú ojú ọgbẹ́ ìbọn lórísiríri.

Nígbà tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀, agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́ọ̀pá ìpínlẹ̀ Òǹdó, Àbàyọ́mìí Jimoh, jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà kan àwọn ku láti ọ̀dọ̀ ọ̀kan lára àwọn aṣáájú àwùjọ ọ̀hún lẹ́yìn tó ṣẹlẹ̀ tán.

Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé ojú ẹsẹ̀ ni àwọn ti fi àwọn òṣìṣẹ́ àwọn pẹ̀lú ẹ̀ṣọ́ aláàbò ẹsẹ̀kùkú, ráńṣẹ́ sí agbègbè ọ̀hún láti mú ètò ààbò gbópan.

Nítẹ̀sìwájú ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n ti rán àwọn ikọ̀ ọ̀hún láti tọpasẹ̀ àwọn oníṣẹ́ ibi náà lọ, tí àwọn ikọ̀ míràn sì dúró lákọ láti dáàbò bo agbègbè ọ̀hún lọ́wọ́ ìkọlù míràn tó bá fẹ́ wáyé.

Iléeṣẹ́ ọlọ́ọ̀pá wá mú u dá àwọn aráàlú lójú pé, gbogbo àwọn tó ń bẹ lẹ́yìn ìkọlù àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ni ọwọ́ yóò bá, ti wọn yóò sì fi ìyà tó tọ́ lábẹ́ òfin jẹ wọ́n.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *