Enimere Àkànbí
Ìjọba oríléèdè Nàìjíríà tí jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn ti ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà tí yóò fi ààyè gba kíkọ́ nípa ìlànà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àwọn tó ní ìpènijà ọ̀rọ̀ gbígbọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ́rẹ̀ káàkiri ilẹ̀ yìí.
Akọ̀wé àjọ elétò ẹ̀kọ́ káárí ayé, Arábìnrin, Aisha Garba, ló jẹ́ kó di mímọ̀ bẹ́ẹ̀ níbi ìṣàmì ayẹyẹ ọjọ́ àwọn ọmọ obìnrin lágbèyé ti ọdún 2025, pẹ̀lú àkòrí, síwájú àyípadà, kọ́ nípa ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àwọn tó ní ìpènijà ọ̀rọ̀ gbígbọ́ lónìí.
Arábìnrin Garba, túbọ̀ fìdí ìpinnu ìjọba àpapọ̀ láti ṣe àgbékalẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ tó lapájá, pàápàá jù lọ, ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ obìnrin, pẹ̀lú ìtọ́kasí pé ìjọba ti tẹ̀síwájú láti ṣe nǹkan tó yẹ lórí ètò ẹ̀kọ́ àti ìrólágbára àwọn ọmọ obìnrin.
Bákan náà ló sọ pé ìjọba mọ̀ pé ẹ̀kọ́ nìkan ló le è mú ìdọ́gba wà, tó sì jẹ́ pé kó lapájá nìkan ni igi lẹ́yìn ọgbà rẹ̀.
Arábìnrin Garba, sọ pé ìdí nìyí tí ìjọba fi ń da ọwọ́ iṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn láti ríi dájú pé wọn kò já ọmọ kankan sílẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, àkòrí ayẹyẹ ọ̀hún ní ọdún yìí jẹ́ ìpè, ìgbésẹ̀ akin àti ìránraẹnilétí tó yẹ, pé ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láì yọ igun kankan sílẹ̀, jẹ́ nǹkan tó yẹ kí ìjọba ríi dájú pé gbogbo ọmọ obìnrin, tó fi mọ́ àwọn tó ní ipenija ọ̀rọ̀ gbígbọ́, ni wọ́n ṣe nǹkan tó yẹ fún àti ìrólágbára láti léwájú àyípadà tí wọ́n ń fi ojú sùn.

Nínú ọ̀rọ̀ alákòóso kejì fọ́rọ̀ ètò ẹ̀kọ́ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́nbìnrin Suwaiba Ahmad, sọ pé ìṣàkóso tí Ààrẹ Bọ́la Tinúbú ń tukọ̀ rẹ̀, yóó ṣe gbogbo nǹkan tó ní lágbára láti yọ gbogbo ohun tó ń ṣe ìdíwọ́ fún àǹfààní tó gbòòrò àti ríríi dájú pé gbogbo ọmọ obìnrin láì fi ipò tàbí ohunkóhun ṣe, ní ààyè lójú ọ̀nà àṣeyọrí nínú ètò ẹ̀kọ́ àti ìgbé ayé.









Leave a Reply