SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Àjọ OYSIEC, NSCDC Ṣẹ Ìfẹsẹ̀múlẹ̀ Ajọṣepọ̀ Fún Ètò Ìdìbò Tó Mányánlórí

img 20260521 wa0002

Enimere Àkànbí
Lójúnà láti ríi dájú pé ìdìbò tó fẹ́ wáyé láwọn ìjọba ìbílẹ̀ mányánlórí, kó sì lọ ní àlàáfíà, Àjọ elétò ìdìbò nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́ (OYSIEC) àti Àjọ ààbò ara ẹni lààbò ìlú, (NSCDC) ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ti túbọ̀ fìdí ìmúratán láti ṣe ìrólágbára fún àjọṣepọ̀ hàn.

Èyí wáyé nígbà tí Alága Àjọ elétò ìdìbò nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, OYSIEC, Ọ̀mọ̀wé Afees Adéníyì, ṣe àbẹ̀wò sí olú iléeṣẹ́ Àjọ NSCDC nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, èyí tó ń bẹ ní agbègbè Agodi, nílùú Ìbàdàn.

Ọ̀mọ̀wé Adéníyì, túbọ̀ jẹ́ kó di mímọ̀ pé Àjọ ọ̀hún ti ṣe tán láti ṣètò ìdìbò tó mányánlórí àti èyí tí yóò lọ ní àlàáfíà, pẹ̀lú àfikún pé àwọn ti ṣe gbogbo ètò kalẹ̀, láti mú àfojúsùn náà wá sí ìmúṣẹ.

Ó túbọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ohunkóhun kò tíì yẹ ètò ìdìbò náà tí yóò wáyé ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ tó ń bẹ nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, kúrò ní ọjọ́ kọ̀kàndínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.

Alága Àjọ OYSIEC, fi àkókò náà gbóríyìn fún Àjọ NSCDC, fún àtìlẹyìn ìgbà gbogbo àti ìwà akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí wọ́n ti fi hàn nínú àwọn ètò ìdìbò tí Àjọ ọ̀hún ti ṣe sẹ́yìn.

Ó fi ìgboyà hàn nínú Àjọ NSCDC pé wọn yóò tún lo gbogbo nǹkan tí wọ́n ní láàká láti fi ṣe iṣẹ́ takuntakun tọ bí ètò ìdìbò ọ̀hún yóò ṣe kẹ́sẹjárí pẹ̀lú àlàáfíà, ó sì tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé Àjọ elétò ìdìbò náà yóò tẹ̀síwájú láti má a ṣe iṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn, láti ríi dájú pé wọn kò fi igbá kan bọ̀ ìkan nínú lákòókò ètò ìdìbò.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Ọ̀gá àgbà Àjọ NSCDC, nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, Augustine Padonu, fi Àjọ OYSIEC lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn yóò ṣe ojúṣe àwọn ní ìbámu pẹ̀lú àgbékalẹ̀ òfin, pàápàá jù lọ nínú pípèsè ààbò tó péye fún ètò ìdìbò, ìpèsè ààbò fún àwọn nǹkan ẹlẹgẹ́ nínú èròjà ìdìbò àti ríríi dájú pé àlàáfíà jọba ṣáájú, lákòókò àti lẹ́yìn ètò ìdìbò.

Bákan ló sọ pé àjọṣe tó nítumọ̀ láàrin àwọn iléeṣẹ́ aláàbò jẹ́ nǹkan gbòógì fún ètò ìdìbò tó mányánlórí àti èyí tí yóò lọ ní àlàáfíà, ó fi kún pé Àjọ NSCDC kò ní tẹ̀tì láti má a kó àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ òṣìṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, láti ríi dájú pé ohun gbogbo lọ létòletò, kí ààbò sì péye káàkiri ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lákòókò ètò ìdìbò.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *