SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ilé-Ẹjọ́ Rán Alákòóso Ìjọba Nígbà Kan Rí Lọ Ẹ̀wọ̀n Ọdún Márùndínlọ́gọ́rin

images (6)

Enimere Àkànbí
Onídáàjọ́ James Ọmọ́tọ́ọ̀ṣọ́, ti ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀, ti rán ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ Alákòóso ìpèsè iná ọba lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Saleh Mamman, lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùndínlọ́gọ́rin, nítorí ẹ̀sùn fífi ọ̀nà ẹ̀rú kó bílíọ́ọ̀nù mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nínú owó ìlú, èyí tí Àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ lẹ́ka ọrọ̀ ajé àti ìnákúnàá owó lórílẹ̀èdè yìí, EFCC, fi kàn-án.

Ìjìyà ọ̀hún ni wọ́n piyamọ sílẹ̀ fún Ọ̀gbẹ́ni Mamman, tí kò fi ojú hàn ní ilé ẹjọ́.

Ẹ̀sùn méjìlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Àjọ EFCC kà sí Ọ̀gbẹ́ni Mamman, lọ́rùn, ní ilé ẹjọ́ náà sọ pé ó jẹ̀bi rẹ̀, tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ẹ̀sùn ọ̀hún kọjá ohun tí èèyàn ni láti má a ṣiyèméjì lé lórí.

Onídáàjọ́ Ọmọ́tọ́ọ̀ṣọ́, pàṣẹ pé Ọ̀gbẹ́ni Mamman, gbọ́dọ̀ ṣe ẹ̀wọ̀n ẹ̀sùn kọ̀ọ̀kan tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ méjìlá lọ́ọ̀tọ̀tọ̀, èyí tó jẹ́ kí àpapọ̀ ọdún tí yóò lò lẹ́wọ̀n jẹ́ márùndínlọ́gọ́rin.

Ilé ẹjọ́ ọ̀hún fún alákòóso nígbà kan rí náà ní ẹ̀wọ̀n ọdún méje fún ẹ̀sùn kínní, kejì, kẹta, kẹfà, kẹjọ, kẹsàn-án, kẹwàá, kọkànlá àti kejìlá, láì gbọdọ̀ sí àǹfààní fún owó ìtanràn.

Bákan náà ni Adájọ́, ní kí ó fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta jura fún ẹ̀sùn kẹrin pẹ̀lú àǹfààní láti san owó ìtanràn àti ẹ̀wọ̀n ọdún méjì fún ẹ̀sùn karùn-ún, láì fi ààyè sílẹ̀ fún owó ìtanràn.

Onídáàjọ́ Ọmọ́tọ́ọ̀ṣọ́, ṣàlàyé pé, Ọ̀gbẹ́ni Mamman, mọ̀ọ́ mọ̀ má fi ojú hàn ní ilé ẹjọ́ ọ̀hún ni, láti leè fi da ìṣàkóso ilé ẹjọ́ láàmú.

Ilé ẹjọ́ ọ̀hún gbà pẹ̀lú Àgbàọ̀jẹ̀ agbẹjọ́rò Rótìmí Oyèdépò, tó gba ẹnu sọ fún Àjọ EFCC, pé bí olùjẹ́jọ́ kò ṣe fi ojú hàn ní ilé ẹjọ́, ìdájọ́ náà yóò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú òfin ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́ẹ̀dógún, tó fi ààyè sílẹ̀ fún ìṣàkóso ìdájọ́ ìwà ọ̀daràn.
Sẹ́gun Adélakùn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *