SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Gómìnà Mákindé Kéde Èróńgbà Láti Di Ààrẹ Oríléèdè Nàìjíríà Lọ́dún 2027

img 20260514 155544 408

Enimere Àkànbí
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé, ti fi èróńgbà hàn láti díje dupò Ààrẹ oríléèdè Nàìjíríà nínú ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.

Níbi ìwọ́de ìta gbangba alágbára tí igun Ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party (PDP) tí Mákindé ń kó sódì àti Ẹgbẹ́ òṣèlú All People’s Movement (APM) jùmọ̀ ṣe níwájú gbàngàn Màpó, Ìbàdàn, ni ó ti fi èróńgbà náà hàn.

Gómìnà Mákindé, gba àwọn Ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò níyànjú láti ṣe ara wọn lọ́kàn tako ohun tó ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi akitiyan àmọ̀ọ́ṣe Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) tó ń ṣe ìṣàkóso ìjọba oríléèdè yìí ń ṣe láti sọ oríléèdè yìí di ẹlẹ́gbẹ́ òṣèlú kan.

Ó ṣàlàyé pé oríléèdè Nàìjíríà kò ṣe àmúlò ìjọba àwarawa tí atọ́nà ètò òṣèlú rẹ̀ leè ṣe ìfògùn gbárí ìdíje dupò tí Ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń bẹ nípò kò ní ti ọwọ́ bọ̀ lójú.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, wá gba àwọn ọmọ Nàìjíríà níyànjú láti múra sí ọ̀rọ̀ ara wọn ju kí wọ́n jẹ́ olùwòran nìkan lọ, ó sì fi ògun rẹ̀ gbárí pé àjùmọ̀ kópa àwọn aráàlú, pàápàá jù lọ àwọn tó ti tó ìbò ó dì nínú ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, yóò ṣe atọ́nà ayipade ọ̀tun nínú àtimáaṣe bọ̀ oríléèdè yìí.

Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ alága Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, Dayọ̀ Ògúngbénró, tó ṣe àpèjúwe ìwọ́de ìta gbangba alágbára, náà gẹ́gẹ́ bíi èyí tí yóò bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwọ́de, ó sì fi ìgbàgbọ́ hàn pé àjọṣe pọ̀ Ẹgbẹ́ òṣèlú méjèèjì yóò mú àṣeyọrí wá fún ipò Ààrẹ, Gómìnà, ilé aṣòfin àgbà àti ilé aṣòfin ìpínlẹ̀, tí àwọn yóò jùmọ̀ yan olùdíje fún nínú ètò ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́dún tó ń bọ̀.

Nígbà tí Alága Ẹgbẹ́ òṣèlú APM lórílẹ̀èdè Nàìjíríà lápapọ̀, Ọ̀mọ̀wé Yusuf Naman Dantale àti Akọ̀wé Ẹgbẹ́ òṣèlú APM lórílẹ̀èdè Nàìjíríà lápapọ̀, Ayọ̀délé Ọyádèyí, pè fún àyípadà rere nínú àgbékalẹ̀ ètò ìṣàkóso oríléèdè Nàìjíríà.

Wọ́n tọ́ka sí ètò ààbò tí kò péye tó, ìjínigbé, àìní àǹfààní sí ètò ìlera tó péye àti ìnira àìrí owó fi ṣayé tó bá àwọn ọmọ Nàìjíríà, gẹ́gẹ́ bíi ìdí tí àwọn ṣe pa ọwọ́ pọ̀ láti gba oríléèdè Nàìjíríà sílẹ̀, fún àǹfààní àwọn aráàlú.

Ṣáájú ni Ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party (PDP) tí Mákindé ń kó sódì àti Ẹgbẹ́ òṣèlú All People’s Movement (APM) jùmọ̀ ti ọwọ́ bọ ìwé àfẹnukọ̀ àjùmọ̀ṣepọ̀ ní olú ilé ìyá Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ní ẹkùn ìwọ̀-oòrùn oríléèdè Nàìjíríà.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *