Enimere Àkànbí
Gbajúmọ̀ olórin Afro, ọmọ oríléèdè Nàìjíríà, Níníọlá Àpáta, ti kéde ìpapòdà ọkọ rẹ̀.
Níníọlá tó kọrin gba onírúurú àmì ẹ̀yẹ, ló jẹ́ kó di mímọ̀ nínú àwọn nǹkan tó gbé sójú òpó ayélujára Instagram.
Ọkọ Níníọlá, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Michael Ndika, ló jẹ́ Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ìròyìn àti ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, NaijaReview, tí wọ́n ti ń ṣe ìfọnrere orin Afro àti àwọn orin ilẹ̀ adúláwọ̀, kí ọlọ́jọ́ tó dé.
Olórin ọ̀hún tó jẹ́ kó di mímọ̀ pé ọdún mẹ́tàlá ni àwọn fi jọ ṣe tọkọtaya, ṣàpèjúwe ikú ọkọ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi àmúwá Ọlọ́run
Ohun tó fa ìpapòdà ọkọ Níníọlá, ni ẹnikẹ́ni kò mọ̀ ní àkókò tí à ń kọ ìròyìn yìí, nítorí pé olórin náà má a ń fi nǹkan nípa ara rẹ̀ pamọ́ fún àwùjọ láti mọ́ ọ ti ojú bọ̀.
Níníọlá, ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì, ló di gbajúgbajà lẹ́yìn tí ó fakoyọ jùlọ lọ́dún ẹgbàá-lé-mẹ́tàlá, nínú ètò kan tí wọ́n ma fi ń ṣe àwárí àwọn tó ní ẹ̀bùn orin ní ilẹ̀ adúláwọ̀ (Project Fame West Africa)
Àbúrò rẹ̀ ni gbajúgbajà olórin n nì, Tẹ́nìọlá Àpáta tí àwọn kan mọ̀ sí Tẹ́nì-Makanákì.











Leave a Reply