SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ṣèlérí Ètò Ààbò Lákòókò Ètò Ìdìbò Ìbílẹ̀

img 20260428 wa0003

….Àwọn Aṣáájú Àjọ OYSIEC Ṣàbẹ̀wò Sí Ọ̀gá Ọlọ́pàá

Enimere Àkànbí

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti fi àwọn aráàlú àti olùgbé rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pé ètò ààbò tó péye yóò wà fún wọn ṣáájú, lákòókò àti lẹ́yìn ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n piyamọ pé yóò wáyé ní ọjọ́ kọ̀kàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.

Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Olúgbénga Abímbọ́lá, ló fi àwọn aráàlú lọ́kàn balẹ̀ bẹ́ẹ̀ lákòókò tó ń gba àwọn aṣáájú àti ìgbìmọ̀ aláṣẹ Àjọ elétò ìdìbò nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, (OYSIEC) ní àlejò ní olú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá náà tó ń bẹ ní agbègbè Ẹlẹ́yẹlé, Ìbàdàn.

Ọ̀gbẹ́ni Abímbọ́lá, ṣàlàyé pé àlàáfíà àyíká ṣe kókó fún àgbékalẹ̀ ètò ìdìbò tó mányánlórí, tó sì jẹ́ kó di mímọ̀ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti gbaradì láti ríi dájú pé ààbò tó péye wà fún ẹ̀mí àti dúkìá àwọn aráàlú lákòókò ètò ìdìbò ọ̀hún.

img 20260428 wa0001

“Mo fẹ́ mú u dá alága àti àwọn àṣọmọ̀gbe wọn lójú pé a ó ṣe àtilẹyìn ìdá ọgọ́rùn-ún fún wọn lákòókò ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó ń bọ̀ lọ́nà.

“A ti ń ṣe, a sì ni dáwọ́ dúró, nítorí pé kò sí ọ̀nà míì tí a leè fi ṣètò ìdìbò tó péye fún àwọn aráàlú, láì sí ààbò tó péye.

“Ètò ìdìbò ọdún yìí, kò ní yàtọ̀ sí ti àwọn ti àtẹ̀yìn wá. A ó da ọwọ́ iṣẹ́ pọ̀ dáadáa. A ó sì fi han àwọn ìpínlẹ̀ míì pé a lè ṣé. Inú mi dùn pé ẹ wá”

Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ Alága Àjọ OYSIEC, Ọ̀mọ̀wé Afees Adéníyì, ṣàlàyé pé àbẹ̀wò ọ̀hún ni láti fi tó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá náà létí, èróńgbà àwọn láti ṣe ètò ìdìbò àlàáfíà àti èyí tí kò ní ní ìfúngun mọ́ nínú.

Ọ̀mọ̀wé Adéníyì, jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ má a ń kọminú nípa ààbò wọn láwọn ọjọ́ tí ètò ìdìbò bá ń wáyé, ó sì tẹnu mọ́ ìdí pàtàkì tí àjọṣe pọ̀ tó gbópan fi gbọ́dọ̀ wà pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá, lójú náà láti pèsè àyíká tó péye ṣáájú, lákòókò àti lẹ́yìn ètò ìdìbò.

Ó sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti ṣe ìkún lọ́wọ́ fún ìrẹ́sẹ̀walẹ̀ àṣà àti òfin láwọn ibùdó ìdìbò àti láti ríi dájú pé ẹ̀mí kankan kò ṣòfò lákòókò tí ètò ìdìbò bá ń lọ lọ́wọ́.

Alága Àjọ OYSIEC, gbóríyìn fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, fún àtìlẹyìn wọn ìgbà gbogbo lákòókò ètò ìdìbò tó wáyé sẹ́yìn, ó sì gba iléeṣẹ́ ọlọ́pàá níyànjú láti má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun gbún àjọṣe pọ̀ wọn.

“A wà níbi lónìí láti fi tó o yín létí nípa ètò ìdìbò tí yóò wáyé lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù kejìlá, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, àti láti jẹ́ kí ẹ mọ nípa àwọn nǹkan tí a nílò.

“A rí àtìlẹyìn tó gbópan gbà lọ́wọ́ iléeṣẹ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìnlélógún, a sì mọ̀ọ́ lóore. A ń fojú sọ́nà fún àtìlẹyìn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yín, ní bí a ṣe ń gbaradì fún ètò ìdìbò tó ń bọ̀”

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *