Enimere Àkànbí
Alága Àjọ elétò ìdìbò lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Joash Àmúpìtàn, ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìdánilójú ìrólágbára àti ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ni ó mú òun tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ náà tí ìjọba àpapọ̀ gbé fún òun.
Ọ̀gá àgbà Àjọ INEC, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìsìn ìdúpẹ́ ìdágbére tí ìjọ onítẹ̀bọmi lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, se fún Ààrẹ ìjọ ọ̀hún lápapọ̀ tó ń fi ipò sílẹ̀, Israel Akanji àti aya rẹ̀, Victoria Akanji, ṣàlàyé pé òun kò bá kọ ìyànsípò náà, ká ní pé Ọlọ́run kò fún òun ní ìdánilójú àtìlẹyìn náà.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìpinnu rẹ̀ láti bọ́ sí ipò ọ̀hún, Ọ̀jọ̀gbọ́n Àmúpìtàn, sọ pé ìdánilójú náà ló ti ń ṣe atọ́nà òun gẹ́gẹ́ bíi aṣáájú Àjọ elétò ìdìbò, pẹ̀lú u gbogbo ìdojúkọ àti bí ojúṣe òun láti ṣe àmójútó àti ìṣàkóso ètò ìdìbò oríléèdè yìí ṣe pẹ̀ka tó.
Ó sì fi ọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé kó sì ìdojúkọ tí ó leè wá tí ó le ju agbára Ọlọ́run lọ láti ṣẹ́gun rẹ̀ fún òun.
Bákan náà ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Àmúpìtàn, gba àwọn ọmọ Nàìjíríà níyànjú láti má a súre fún Àjọ INEC àti àṣeyọrí ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, ó sì fi ìgbàgbọ́ sọ pé àṣeyọrí ètò ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà yóò kọjá àwọn tó ti wáyé sẹ́yìn lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.











Leave a Reply