SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Alága Àjọ OYSIEC Gba Àmì Ẹ̀yẹ Aṣojú ASUP tilé Ẹ̀kọ́ OYSCATECH

IMG 20251219 WA0003

Enimere Àkànbí
Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ làwọn ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe lórílẹ̀èdè yìí, (ASUP) ẹ̀ka ti ilé ẹ̀kọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ìmọ̀-ẹ̀rọ, (OYSCATECH), tó ń bẹ nílùú Igbóọrà, tí fi àmì ẹ̀yẹ “Aṣojú Ẹgbẹ́ ASUP” dá Alága tuntun Àjọ elétò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, (OYSIEC) Ọ̀mọ̀wé Babátúndé Afeez Adéníyì, lọ́lá.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣáájú Ẹgbẹ́ náà ṣe ṣàlàyé, àmì ẹ̀yẹ ọ̀hún ni wọ́n gbé fún Ọ̀mọ̀wé Adéníyì, tó ti fìgbà kan rí jẹ́ alága wọn, láti fi ìmọrírì hàn sí ipa ribiribi tó kó nínú ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún àti Ẹgbẹ́ náà lákòókò tó fi wà pẹ̀lú wọn.

Lára àwọn gbajúmọ̀ tí wọ́n tún fún ní àmì ẹ̀yẹ níbi ayẹyẹ ìparí ọdún tí Ẹgbẹ́ náà ṣe nínú gbọ̀ngàn oníjòkóò ẹlẹ́gbẹ́rin tó ń bẹ nínú ilé ẹ̀kọ́ OYSCATECH ni, Olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ Rédíò ìkànnì Solutions, tó ń bẹ ní ìlú Ìbàdàn, Àgbà-oyè Adégbóyèga Taofeek Adégòkè (FCA), Alága ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìṣàkóso ilé ẹ̀kọ́ OYSCATECH, Ọ̀mọ̀wé Amúsàń Dámiláre Gideon, Alága nígbà kan rí, ní ìjọba ìbílẹ̀ Àrìnringbùngbùn Ìbáràpá, Ọnarébù Sharafa Ọlanioye àti Ọnarébù AbdulRasheed Ọláńrewájú Ariwoọlá.

IMG 20251219 WA0004 225x300

Nígbà tó ń gbé àmì ẹ̀yẹ ọ̀hún fún Alága Àjọ OYSIEC, Olùdarí Ẹgbẹ́ ASUP ní ẹkùn kẹta (Zone “C) Ọ̀mọ̀wé Nurudeen Adékúnlé Masopa, gbóríyìn fún Ọ̀mọ̀wé Adéníyì fún ipa rere tó fi sílẹ̀, pẹ̀lú ìtọ́kasí ìfararúbọ, ìgboyà àti ìforítì, tí ó fi hàn làwọn àkókò tó fi jẹ́ alága Ẹgbẹ́ ASUP, èyí tó ṣe àpèjúwe gẹ́gẹ́ bíi ohun tó ran ìdàgbàsókè Ẹgbẹ́ náà lọ́wọ́.

Nínú ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ Alága Àjọ OYSIEC, Ọ̀mọ̀wé Babátúndé Afeez Adéníyì, ó ṣe àpèjúwe àmì ẹ̀yẹ náà gẹ́gẹ́ bíi ohun tí ó wá lákòókò tí òun ṣì wà láàyè, tí kìí ṣe pé wọ́n fi ń ṣe ìrántí òun.

Alága Àjọ OYSIEC ṣàlàyé síwájú pé àmì ẹ̀yẹ àti iyì tí wọ́n bù kún òun, yóò túbọ̀ mú òun fara jìn àti láti túbọ̀ fara ṣe iṣẹ́ fún ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè Ẹgbẹ́ ASAP àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ ẹ̀.

Ọ̀mọ̀wé Adéníyì, tọ́ka sí àtìlẹyìn, iṣẹ́ àjùmọ̀ṣepọ̀, ìfararúbọ àti akitiyan gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ohun tó bí àṣeyọrí tí òun ṣe nígbà tí òun fi jẹ́ alága Ẹgbẹ́ ASUP ní ilé ẹ̀kọ́ OYSCATECH.

Ó tún lo àkókò náà fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé, fún ìlànà tó fi ń bá àwọn aṣáájú Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ làwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó jẹ́ ti ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, lò, ó sì ṣe àpèjúwe Gómìnà Mákindé, gẹ́gẹ́ bíi elééti gbáròyé.

Bákan náà ni Ọ̀mọ̀wé Adéníyì, kan sára sí àwọn akọni tó já fún ìdágbásókè àti ìṣọ̀kan Ẹgbẹ́ ọ̀hún, ṣùgbọ́n tí wọ́n ti rebi àgbà ń rè, wọ́n sì dákẹ́ ìṣẹ́jú kan fún àwọn akọni ọ̀hún tó ti lọ.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *