SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ìdá Kan Ni Màá Ṣe, Màá Yanjú Gbogbo Nǹkan Tó Ń Fa Ìfẹ̀hùnúhàn Lórí Ọ̀nà Olóbìrípo – Gómìnà Mákindé

IMG 20251126 WA0028

Enimere Àkànbí

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé ti fi gbogbo àwọn tó ní ilẹ̀ tàbí ilégbèé sí àwọn agbègbè tí àkànṣe iṣẹ́ ojú ọ̀nà olóbìrípo Ìbàdàn, gbà kọjá, lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo nǹkan tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wọn lórí ìgbésẹ̀ ọ̀hún ni ìṣàkóso òun yóò wá ojútùú sí, láì ní fi sílẹ̀ de ìṣàkóso tó ń bọ̀.

Gómìnà Mákindé, ṣèlérí yìí ní agbègbè Ológúnẹrú, Ìbàdàn, lákòókò tó lọ rèé yọjú sí àwọn tó ní ilẹ̀ àti ilégbèé, ní àwọn agbègbè tí àkànṣe iṣẹ́ ìdàgbàsókè ọ̀hún gbà kọjá ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìdó.

Gómìnà tó fi àkókò yìí kéde pé Àjọ tó ń ṣe àmójútó ìdàgbàsókè ìgboro ìlú àti àwọn ìlú tuntun ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni yóò má a ṣe ìṣàkóso àti àmójútó àwọn ìṣòro tó jẹ yọ lórí àkànṣe iṣẹ́ ọ̀nà olóbìrípo náà, gba gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn níyànjú láti ṣa àwọn aṣojú mẹ́wàá jọ, tí yóò ṣe iṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Àjọ ọ̀hún fún ìmúṣẹ àwọn nǹkan tó jẹ igun méjèèjì lógún.
‎
Bákan ló tún ṣèlérí pé, àwọn aṣojú ìjọba kò ní wó ilé kankan mọ́, láì san ẹ̀tọ́ tó yẹ fún wọn.

Nígbà tó ń túbọ̀ fìdí ìmúratán ìṣàkóso rẹ̀ sí àkóyawọ́ àti ìlànà gbangbalàṣáńta, múlẹ̀, Gómìnà Mákindé, fi àwọn olùgbé àti ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, lọ́kàn balẹ̀ pé òun kò ní já wọn kulẹ̀.

Ó wá rọ àwọn tó ní ilégbèé ní àwọn agbègbè tí àkànṣe iṣẹ́ ojú ọ̀nà olóbìrípo Ìbàdàn gbà kọjá, láti má ṣe kà á kún, àmì ìparun yòówù tí wọ́n bá ṣe sí àwọn ilé gbogbo tí wọ́n kọ́ sí ìkọjá ààdọ́jọ mítà ilẹ̀ tí ìjọba bù ní ẹ̀gbẹ́ kìnní àti ìkejì àkànṣe iṣẹ́ ọ̀hún, tó sì mú u dá wọ́n lójú pé, gbogbo iṣẹ́ ìdàgbàsókè náà, kò ní kọjá òdiwọ̀n ọ̀hún.

Gómìnà Mákindé, wá jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìdá kan nínú u mẹ́rin àkànṣe iṣẹ́ ojú ọ̀nà olóbìrípo, ṣùgbọ́n òun yóó la ojú ọ̀nà náà sílẹ̀, fún ìṣàkóso tó ń bọ̀ láti tẹ̀síwájú lórí rẹ̀.

IMG 20251126 WA0029 300x190

Nígbà tí olórí ìgbìmọ̀ tí Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Lájọdà, gbé kalẹ̀ láti má a mójútó ọ̀rọ̀ gbogbo tó ní ṣe pẹ̀lú káràkátà ilẹ̀ ní ìlú Ìbàdàn, àgbàọ̀jẹ̀ Agbẹjọ́rò nnì, Níyì Akíntọ́lá, ń sọ̀rọ̀, ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìjọba ìbílẹ̀ Ìdó kò sí lára àwọn agbègbè tí ó yẹ kí àkànṣe iṣẹ́ náà dé, àwọn aṣáájú àti àwọn tó lórúkọ tó wá láti ìjọba ìbílẹ̀ ọ̀hún, ló bẹ̀bẹ̀ fún-un.

Akíntọ́lá, ṣàlàyé síwájú pé, àkànṣe iṣẹ́ náà ló ti wà ní àkọsílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́, nítorí pé àwọn ìṣàkóso àtẹ̀yìn wá, kò ní ìgboyà, àmúyẹ àti àwọn èròjà tí wọ́n lè è fi ṣe àmúṣẹ rẹ̀.

Àgbàọ̀jẹ̀ Agbẹjọ́rò, ọ̀hún wá dirù ẹ̀bi, bí nǹkan ṣe pakasọ yìí ru àwọn tó ń talẹ̀, tí wọn kò sọ irú ilẹ̀ tí wọ́n ń tà, ó sì fi àwọn tó ní nǹkan ìní ní àwọn agbègbè tí àkànṣe iṣẹ́ ìdàgbàsókè ọ̀hún ṣe àkóbá fún, lọ́kàn balẹ̀ pé, Gómìnà Mákindé yóó sọ ẹkùn wọn di ẹ̀rín.

Ṣáájú nígbà tí àwọn tó ṣojú gbogbo àwọn tó ní ilẹ̀ tàbí ilégbèé sí bi àkànṣe iṣẹ́ ojú ọ̀nà olóbìrípo náà, ń sọ̀rọ̀, wọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Gómìnà Mákindé láti wo àwọn ṣe ní àánú, kí ó san ẹ̀tọ́ tó yẹ fún àwọn tí ojú ọ̀nà jẹ ilẹ̀ àti ilégbèé wọn, mú àdínkù bá ilẹ̀ tí ìjọba bù ní ẹ̀gbẹ́ kìnní àti ìkejì àkànṣe iṣẹ́ náà, kí ìjọba rẹ̀ síì ṣe àkọsílẹ̀ ìlànà àti àfẹnukọ̀ tó bá wáyé lórí ọ̀rọ̀ yìí sínú ìwé òfin, kí àwọn ìjọba tó ń bọ̀ le è má a tẹ̀lé ẹ.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *