SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎Àwọn Adájọ́ Nílò Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Àtìgbàdégbà Nípa Ìwàbàjẹ́ Nínú Ìṣàkóso Owó – EFCC

Enimere Àkànbí
Àjọ tó ń gbógun ti ìwàbàjẹ́ lẹ́ka ọrọ̀ ajé àti ìnákúnàá owó lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, EFCC, tí dáàbá pé kí wọ́n máa ṣe ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àtìgbàdégbà fún àwọn Adájọ́ lórílẹ̀èdè yìí, nípa àwọn ìwàbàjẹ́ tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ka ìṣàkóso owó àti owónàá lórílẹ̀èdè yìí.

‎Olórí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ òfin nínú Àjọ EFCC, ẹ̀ka ti ìlú Ìbàdàn, DCE Gift Odibo, ló dáàbá yìí níbi ètò àwùjọ kan.

‎DCE Odibo, ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ Adájọ́ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, ni kò mọ́ nípa àwọn ìwà kòtọ́ tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ka owónàá, èyí tó ma ń fi ara hàn nínú ìṣọwọ́gbé ìdájọ́ wọn kalẹ̀ lórí àwọn ẹjọ́ tí àwọn ti gbé ka iwájú wọn.

‎Bákan náà ló mẹ́nu báà ìdí tí àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn lórílẹ̀èdè Nàìjíríà fi ní láti ṣe àtúngbéyẹ̀wò òfin lọ́nà tí yóò fi bá ìgbà mu, ṣe àmójútó àwọn ìwàbàjẹ́ tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ka ìṣàkóso owó àti owónàá, mú ìdàgbàsókè bá ààbò tó péye fún àwọn olujẹrìí, tó fi mọ́ idasilẹ̀ àkànṣe ilé ẹjọ́ tí yóò má a gbọ́ ẹjọ́ tó dá lórí ìwàbàjẹ́ nínú ìṣàkóso owó àti owónàá, tàbí àwọn ẹjọ́ tó níṣe pẹ̀lú ṣiṣé owó kúmọkùmọ.

‎Nígbà tí òun náà ń sọ̀rọ̀, agbẹnusọ àti olórí ẹ̀ka ìròyìn àti ìpolongo fún àjọ EFCC, DCE Délé Oyèwálé, ṣàlàyé pé lábẹ́ ìdarí Alága Àjọ ọ̀hún, Ọ̀gbẹ́ni Ọlá Olúkóyèdé, Àjọ EFCC ń tẹ̀síwájú láti má a ní àkọsílẹ̀ àwọn àṣeyọrí tó nikimi, nínú ìdojú-ìjà-kọ ìwàbàjẹ́ nínú ìṣàkóso owó àti owónàá.


Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *