SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎3SC Yẹ̀’mọ̀ràn Kano Pillars Tó Kù Díẹ̀ Kó Làá Mọ́’Lẹ̀, Làwọn Olólùfẹ́ Rẹ̀ Bá Yọwọ́ Ìjà

Screenshot 20251012 191245

Enimere Àkànbí
‎Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Shooting Stars Sports Club ilẹ̀ Ìbàdàn, 3SC, tẹ̀síwájú nínú ìfakọyọ àti àyípadà rere tó bá wọn láti bíi ọ̀sẹ̀ bíi mẹ́ta sẹ́yìn, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe lọ rèé ta ọ̀mì ayò kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Kano Pillars, ní ọ̀sẹ̀ kẹjọ líìgì oríléèdè Nàìjíríà.

‎Ìfigagbága náà tó wáyé ní pápáṣeré ìdárayá Sani Abacha, ní ìpínlẹ̀ Kano, ni ìfigagbága ẹlẹ́ẹ̀kẹrin ní sísẹ̀ntẹ̀lẹ́ tí 3SC yóò gbà á láì fi ẹ̀yìn janlẹ̀ níwájú alátakò.

‎Bọ́ọ̀lù tí agbọ́wọ́-ẹ̀yìn Mustapha Jibrin gbá wọnú àwọ̀n ní ìṣẹ́jú mẹ́jọ tí ìfigagbága náà bẹ̀rẹ̀, mú Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Kano Pillars, lékè, tí inú àwọn olólùfẹ́ wọn sì ń dùn, pẹ̀lú onírúurú orin tí wọn ń kọ láti fi má a ṣe ìwúrí fún àwọn agbábọ́ọ̀lù wọn.

‎Kódà, Kano Pillars, tí àwọn olólùfẹ́ wọn tún ma ń dà pè ní Sai Masu Gida, gba ìṣàkóso ìfigagbága ọ̀hún, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà.

‎Bẹ́ẹ̀ àwọn agbábọ́ọ̀lù Shooting Stars, náà kò tẹ̀tì láti máa gbìyànjú agbára wọn láti ríi dájú pé, Kano Pillars, kò gbé àmì mẹ́ta náà lo gbé.

‎Ìfigagbága wọ ìṣẹ́jú mẹ́tàlèéládọ̀ọ́rin ni akọ́nimọ̀ọ́gbá Shooting Stars, Nurudeen Awẹ́roro, fi agbábọ́ọ̀lù ní ọwọ́ iwájú, Adams Mustapha, rọ́pò Abíọ́dún Adégòkè, èyí tó jẹ́ ara ọgbọ́n àtinúdá tó ti ń jẹ́ ẹ lọ́wọ́ láti bíi ọ̀sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn.

‎Ní àkókò tí àwọn agbábọ́ọ̀lù Kano Pillars, ń fi àwọn àǹfààní tí wọn ń rí tàfàlà, ni Mustapha, ṣe àmúlò àǹfààní tó bọ́ síi lọ́wọ́ ní ìṣẹ́jú mẹ́rìnlèéní-ààdọ́rùn-ún fún 3SC láti ta ọ̀mì ayò ní ìlú Kano.

‎Ẹ̀tahóró àwọn alátìlẹyìn tó tẹ́lẹ̀ 3SC lọ, ìgbìmọ̀ akọ́nimọ̀ọ́gbá àti àwọn alákòóso, fò fáyọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú tí kò ṣe é pa mọ́ra.

FB IMG 1760292306957 300x135

‎Èyí ba àwọn olólùfẹ́ àti alátìlẹyìn Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Kano Pillars, lọ́kàn jẹ̀ẹ́, débi wípé wọ́n yabo orí pápáṣeré ìdárayá láti fi ọwọ́ ba àwọn adarí ayò àti àwọn agbábọ́ọ̀lù Shooting Stars Sports Club.

‎Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti fa onírúurú ìbẹnu àtẹ́ lù láti ọ̀dọ̀ àwọn alákòóso eré ìdárayá àti àwọn olólùfẹ́ bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá, tí wọ́n sì pè fún ìgbésẹ̀ akin láti máa fi dènà irúfẹ́ ìwà jàgídíjàgan yìí àti bí ààbò tó péye yóó ṣe máa wà fún àwọn agbábọ́ọ̀lù àti àwọn adarí ayò.

‎Ní báyìí, 3SC yóó padà sí ìlú Ìbàdàn láti lọ gba Abia Warriors, lálejò ní ọ̀sẹ̀ kẹsàn-án líìgì oríléèdè Nàìjíríà, ní pápáṣeré ìdárayá Lékan Salami, nígbà tí Kano Pillars, yóó lọ kojú u Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Barau.

‎Lẹ́yìn ìfigagbága ọ̀sẹ̀ kẹjọ, 3SC fi àmì méjìlá jókòó sí ipò karùn-ún, nígbà tí Kano Pillars, fìkàlẹ̀ sí ipò kẹtàdínlógún pẹ̀lú àmì mẹ́jọ.




Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *