SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ìkòròdú City Sọ Sunday 3SC Di Ìkorò, Musa Pitú Ní Kano

Images 7 1

Enimere Àkànbí
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Ìkòròdú City, padà wàá láti ẹ̀yìn, fi ìyà jẹ Shooting Stars Sports Club, 3SC ilẹ̀ Ìbàdàn, pẹ̀lú àmì ayò méjì sí ẹyọ̀kan.

Ìfigagbága ọ̀uń tó wáyé ní pápáṣerédárayá Mọbọ́lájí Johnson, ní ìlú Èkó, ló jẹ́ ti ọ̀sẹ̀ kejìlá sáà 2024/2025 líìgí orílèdè Nàìjíríà.

Anthony Okachi, ló gbá bọ́ọ̀lù tí 3SC fi yájú sí Ìkòròdú City, wọ inú àwọ̀n, ní ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún lẹ́yìn tí ìfigagbága náà bẹ̀rẹ̀.

Ìṣẹ́jú mẹ́jọ lẹ́yìn tí wọ́n wọlé padà fún abala kejì, ni Ṣọlá Adélaní, ran Ìkòròdú City, lọ́wọ́ láti pa ojú ọrẹ́ dà sí 3SC, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tún mọ̀ sí Olúyọ̀lé Soccer Warlords.

Nígbà tí ó ku ìṣẹ́jú méjì kí ìfigagbága ọ̀hún parí sí ọ̀mì, ni Rivio Ayemwenre, fi ọba lé e fún Ìkòròdú City, láti mú ẹ̀yìn Shooting Stars, balẹ̀.

Ní báyìí, 3SC tí bá ara rẹ̀ ní ipò kejìlá pẹ̀lú àmì mẹ́ẹ̀dógún, nígbà tí Ìkòròdú City, sún sí ipò kẹjọ pẹ̀lú àmì mẹ́tadínlógún, lórí tábìlì líìgí orílèdè Nàìjíríà.

Tó bá di ìfigagbága ọ̀sẹ̀ kẹtàlá, Ìkòròdú City yóó lọ sí òkè ìta láti lọ kojú u Niger Tornadoes, nígbà tí Shooting Stars yóó gba Bayelsa United, ní àlejò ní ìlú Ìbàdàn.

Àwọn èsì ìfigagbága ọ̀sẹ̀ kejìlá yòókù tó wáyé, El-Kanemi Warriors fi àmì ayò kan ṣẹ́ Niger Tornadoes, ní ẹ̀yìn, ọ̀mì ayò méjì-méjì ni àjàkúakátá ìjà tó wáyé ní ààrin Kano Pilars àti Heartland, parí sí ní ìlú Kano.

Àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ́lù méjì nnì, Rabiu Ali àti Ahmed Musa, ló gba Kano Pillars, lọ́wọ́ ẹ̀sín tí Emmanuel Amunike àti àwọn agbábọ́ọ́lù rẹ̀ (Heartland) fẹ́ fi wọ́n ṣe ní ojú ọ̀gọ̀rọ̀ olólùfẹ́ wọn.

Èmi kò jù ọ́, ìwọ kò jù mí, ló wáyé ní ààrin Bayelsa United àti Katsina United, tí wọ́n gbá bọ́ọ̀lù kọ̀ọ̀kan wọ inú àwọ̀n ara wọn, ọ̀mì ayò òfo ló wáyé ní ààrin Remo Stars àti Rivers United.

Enugu Rangers fi àmì mẹ́ta sí méjì ṣe àgbà Bendel Insurance, Sunshine pa Lobi Stars lẹ́kùn pẹ̀lú àmì ayò kan, ọ̀mì ayò kọ̀ọ̀kan ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ní ààrin Abia Warriors àti Enyimba parí sí, nígbà tí Kwara United bá Plateau United wí bí i ìkókó pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òfo.

Ṣáájú ní ọjọ́ àbámẹ́ta ni Akwa United fi àgbà han Nasarawa United, pẹ̀lú àmì ayò kan dondo.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *