SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Olúbàdàn Já Ewé Oyè Lé Ààrẹ Ọlágúnjú Lórí Gẹ́gẹ́ Bíi Mọ́gàjí Agbo Ilé Ọ̀pẹrẹ

Enimere Àkànbí
Àwọn ọmọ agbo ilé Ọ̀pẹrẹ, tó fi mọ́ àwọn abániyọ̀, ló péjúpésẹ̀, ní ọjọ́ ajé, sí ibi ètò tí olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Akinloyè Owólabí Ọlákùlẹ́hìn, ti já ewé oyè lé àgbà amòfin(SAN), Ààrẹ Ísíákà Abíọ́lá Ọlágúnjú, ní orí, gẹ́gẹ́ bíi Mọ́gàjí, agbo ilé Ọ̀pẹrẹ, ní agbègbè Ìsàlẹ̀-Òsì, Ìjọba ìbílẹ̀ Ìwọ̀-oòrùn gúúsù Ìbàdàn.

Alága àjọ tó ń ṣe ìṣàkóso ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, (OYSIEC), Ààrẹ Ísíákà ,(SAN) àti àwọn èèyàn pàtàkì mẹ́jọ mìíràn láti onírúurú agbo ilé, ni Ọba Ọlákùlẹ́hìn, fi òye kàbìtì náà dá ní ọlá, ní ààfin rẹ̀, tó fìdí kalẹ̀ sí agbègbè Òkè-Àrẹ̀mọ, Ìbàdàn.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n já ewé oyè lée lórí tán, Mọ́gàjí Ísíákà Ọlágúnjú,(SAN) fi ẹ̀mí ìmọ̀ oore hàn sí gbogbo mọ̀lẹ́bí, fún bí wọ́n ṣe kàáyẹ fún ipò náà, pẹ̀lú àfikún pé ìdí tí ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa kó ipa nínú ìdàgbàsókè àwùjọ, ni kò ṣe é fi ojú fò dá.

Mọ́gàjí agbo ilé Ọ̀pẹrẹ, Ísíákà Ọlágúnjú,(SAN) wá pè fún ìṣọ̀kan àti àtìlẹyìn àwọn ọmọ agbo ilé rẹ̀, nínú akitiyan láti ríi dájú pé agbo ilé wọn, túbọ̀ gba iyì àti ẹ̀yẹ síi ní ìlú Ìbàdàn, nípa ṣíṣe àwọn àṣeyọrí tó ní ìtumò sí ibẹ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ ọ̀kan lára àwọn olú ọmọ agbo ilé Ọ̀pẹrẹ, ọ̀mọ̀wé Muhammad-Lawal Musa Alóngbìjà, ṣe àpèjúwe Mọ́gàjí Ísíákà Ọlágúnjú,(SAN) gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí òun fi ṣe àwòkọ́ṣe, ó sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti da ọwọ́ iṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, nípa sí ṣe àtìlẹyìn fún-un.

ọ̀mọ̀wé Muhammad-Lawal Musa Alóngbìjà, ṣe àlàyé síwájú pé, òun ro mọ́ọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹbí ló ti gbọ́n, tí wọ́n sì ń yan àwọn tí ó kéré ní ọjọ́ orí láti lọ ṣe ojú agbo ilé wọn, kí òun tó ṣe àtìlẹyìn fún ìgbésẹ̀ fífa Ààrẹ Ísíákà Ọlágúnjú,(SAN) kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mọ́gàjí agbo ilé Ọ̀pẹrẹ.

IMG 20241030 WA0015 300x225

Nígbà tí òun náà ń sọ̀rọ̀, aya Mọ́gàjí tuntun ti agbo ilé Ọ̀pẹrẹ, ọ̀mọ̀wé Olúwaníkẹ́ Ọlágúnjú, tí kò leè pa ìdùnnú ìyànsípò ọkọ rẹ̀ mọ́ra, sọ pé kó sí kọ́núhunkọ́họ kankan nínú ìgbésẹ̀ yíyan ẹni tí ẹbí fi ẹnu kò sí.

Ọ̀mọ̀wé Olúwaníkẹ́ Ọlágúnjú, wá wọ̀ye pé èrè àṣẹsílẹ̀ òhun àtimáaṣebọ̀ tó ní ìtumọ̀ Ààrẹ Ísíákà Ọlágúnjú,(SAN) ní ààrin àwọn èèyàn rẹ̀, ló bí ipò Mọ́gàjí.

Ẹ má gbàgbé ọ̀rọ̀ àmúyangàn àwọn ọmọ Ìbàdàn, tó sọ pé, “Mọ́gàjí Ìbàdàn ju ọba ibòmíràn lọ”.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *