Enimere Àkànbí
Àwọn orogun ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù méjì Real Madrid àti Barcelona figagbága fún ìgbà àkọ́kọ́ ní sáà yìí, nínú líìgì orílèdè Spain, ìfigagbága náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí El Clasico dún-ùn, kódà ó lárinrin.
Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ìfigagbága ọ̀hún wáyé ní Santiago Barnabeu, tó jẹ́ pápáṣerédárayá ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Real Madrid, síbẹ̀ Barcelona, kó ìbáwí fún alátakò rẹ̀ lójú àwọn alákòóso àti ogunlọ́gọ̀ olólùfẹ́ wọn.
Àmì ayò mẹ́rin sí òfo, ni Barcelona fi dá Real Madrid, ní agara, tó sì rí ìdí jókòó dáadáa ní ipò àkọ́kọ́ líìgì orílèdè Spain.
Bákan náà ni ìjákulẹ̀ Real Madrid, fi òpin sí àkọsílẹ̀ ìfigagbága mẹtalèlogójì tí alátakò kankan kò rí ẹ̀yìn wọn fi janlẹ̀ nínú líìgì orílèdè Spain, wọ́n sì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èyí tí Barcelona náà ní, láàrin oṣù kẹrin ọdún 2017 sí oṣù karùn-ún, ọdún 2018.
Kò sí ọ̀kankan nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù méjèèjì, tó rí àwọ̀n ara wọn ní abala àkọ́kọ́ ìfigagbága El Clasico yìí, ṣùgbọ́n abala kejì ni Real Madrid, kan róro ní ìrù, nígbà tí Robert Lewandowski, pẹ̀lú ìrànlọ̀wọ́ Marc Casado, ba ojúlé bàbá alátakò rẹ̀ jẹ́.
Lewandowski, kò bẹ̀sùbẹ̀gbà, tó tún fi gbá bọ́ọ̀lù kejì wọn inú àwọ̀n, nígbà tí Alejandro Balde, fi bọ́ọ̀lù wá orí rẹ̀ lọ, èyí ló mú kí àpapò bọ́ọ̀lù tí atamátàsé ọmọ orílèdè Poland, náà, ti gbá sí àwọ̀n ní sáà yìí fún Barcelona, wọ mẹ́tàdínlógún.
Ọ̀dọ́ agbábọ́ọ́lù, Lamine Yamal, ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún náà mi àwọ̀n àkọ́kọ́ rẹ̀ nínú ìfigagbága El Clasico, nígbà tó fi ìkẹta lẹ̀e, kí Raphinha, tó jẹ́ Balógun náà tó wá fi ọba lé e.
Gbogbo ìgbìyànjú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Real Madrid, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé ìparí ìfigagbága náà, ló fi orí ṣánpọ́n, kódà Kylian Mbappé, tó kópa nínú ìdíje El Clasico fún ìgbà àkọ́kọ́, gbá bọ́ọ̀lù wọ inú àwọ̀n Barcelona ní ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n adarí ayò wọ́ igi lé e, fún ẹ̀sùn pé, ó lúgọ.
Ǹjẹ́ a le è sọ pé Barcelona ti jí padà, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe di kanranjọ́gbọ́n lábẹ́ ìtọ́ni Hansi Flick, ẹ má gbàgbé pé ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ni wọ́n fìyà jẹ Bayern Munich, nínú ìdíje àwọn akọni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù ní ilẹ̀ aláwọ̀funfun.










Leave a Reply