Enimere Àkànbí
Fún Ìgbà àkọ́kọ́ ní sáà 2024/2025 líìgì orílèdè England, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Arsenal, ṣubú ní ojú ìjà, nígbà tí Bournemouth, yà àwọn àti àwọn olólùfẹ́ wọn lẹ́nu, pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo, ní pápá ìṣerédárayá Vitality.
Èyí rí bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí adarí ayò, Rob Jones, lé agbábọ́ọ́lù ní ọwọ́ ẹ̀yìn fún Arsenal, William Saliba, jáde kúrò ní orí i pápá, nítorí pé ó ṣe Evanilson, ní ẹ̀pa.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún tó dín àwọn agbábọ́ọ́lù Arsenal, kù sí mẹ́wàá, ló wáyé nígbà tí agbábọ́ọ́lù ọ̀uń, ń gbìyànjú láti, bo akẹgbẹ́ rẹ̀, Leandro Trossard, tó ṣe àṣìṣe, ní àṣírí, tó sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ọmọ orílèdè France, náà, Saliba, yóó gba káàdì pupa, láti ìgbà tí ó ti ń gbá bọ́ọ́lù àláfẹsẹ̀gbá.
Bó ti lẹ̀ jẹ́ pé ní sáà yìí, kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn agbábọ́ọ́lù Arsenal, yóò dínkù sí mẹ́wàá, nínú ìfigagbága EPL, kódà ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n ń kọjú Manchester City, ṣùgbọ́n ti Bournemouth, tó wáyé ní ọgbọ́n ìṣẹ́jú, kọjá ohun tí wọ́n lérò.
Lóòtọ́, wọ́n gbìyànjú láti dá ààbò bo ààwọn wọn, ṣùgbọ́n àádọ́rin ìṣẹ́jú ni Bournemouth, gbé nǹkan gba ẹ̀ẹ̀yìn wọn lọ, nígbà tí Clever fi bọ́ọ́lù àgbésígungbá, wá Ryan Christie, lọ, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Justin Kluivert, tí òun náà sí kó iná yáa.
Ìṣẹ́jú mẹ́sàn-án ní ẹ̀yìn ìgbà náà, ni Kluivert, fi bọ́ọ́lù golí wò mí kí n gbá a, tí aṣọ́lé Arsenal, David Raya, ṣe okùnfà, nígbà tó gbé Evanilson ṣubú, sọọ́ di àmì ayò méjì sí òdo.
Ìjáwé olúborí yìí ṣeyebíye púpọ̀ fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Bournemouth, tí ó pàdánù ìfigagbága mẹ́rin tó gbá sẹ́yìn nínú líìgì sáà yìí, wọ́n sì ti ní àǹfààní láti jókòó sí ipò kẹwàá lórí àkàbà líìgì orílèdè England, Arsenal, fi ìkàlẹ̀ sí ipò kẹta, pẹ̀lú àmì mẹ́tàdínlógún.
Liverpool àti Manchester City, tí kò tíì gbá ìfigagbága tii, ló di ipò kínní àti ìkejì mùú, pẹ̀lú àmì méjìdínlógún àti àmì mẹ́tàdínlógún.
Láti ọjọ́ kejì kérésìmesì ọdún 2019, tí Mikel Arteta, ti ń kó ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Arsenal sódì, àwọn agbábọ́ọ́lù rẹ̀, ti gba àpapọ̀ káàdì pupa méjìdínlógún, nínú líìgì orílèdè England, èyí tó fi márùn-ún pọ̀ ju àwọn akẹgbẹ́ wọn yòókù lọ.
Ohun tó kàn báyìí fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Arsenal, ni làti gba Shahktah Donesk, ní àlejò, nínú ìdíje àwọn akoni UEFA, tí yóó wáyé ní ọjọ́ ìṣègùn.










Leave a Reply