SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ìlú Ìbàdàn Ń Rọ́ Tìtì Fájọ̀dún Ẹ̀ṣọ́ Orí Lágbáyé Tó Fẹ́ Wáyé Lọ́la

IMG 20251223 WA0009

Enimere Àkànbí
Àjọ̀dún Ẹ̀ṣọ́ orí lágbáyé (World Headdress Celebration) ẹlẹ́ẹ̀kéjì irúurẹ̀ tí Ẹgbẹ́ ọmọ Yorùbá Àtàtà (Omo Yoruba Atata Socio-cultural Initiative, OYASI) ṣe àgbékalẹ̀, yóò wáyé ní ọ̀la, tí ṣe ọjọ́ àìkú, ní gbàgede Erédàárayá bọ́ọ̀lù ẹlẹ́yin lórí kankéré, nínú pápáṣèrédárayá Lékan Salami, tó ń bẹ ní agbègbè Adámásingbà, Ìbàdàn, bẹ̀rẹ̀ láti aago méjìlá ọ̀sán.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ yọ nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ Alága Ẹgbẹ́ OYASI, Ọ̀gbẹ́ni Ọláwálé Àjàó, níbi ayẹyẹ náà ni wọn yóò ti ṣe àfihàn onírúurú adé, fìlà àti gèlè àṣà káàkiri àgbáyé, nítorí náà wọ́n gba gbogbo àwọn tó fẹ́ wá síbi ayẹyẹ ọ̀hún láti lo nǹkan Ẹ̀ṣọ́ Orí bí fìlà àti gèlè.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn gbajúmọ̀ Ọ̀mọ̀wé nípa Àṣà àti ìṣe, bíi Àràbà ìlú Òṣogbo, Àràbà Ifáyẹmí Ẹlẹ́bùìbọn, Olúwòó ti ìlú Ìwó, Ọba Abdulrasheed Adéwálé Àkànbí àti Àgbà-ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé ni, Alàgbà Débọ̀ Awe, yóò ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa pàtàkì ẹ̀ṣọ́ orí láàrin àwọn ọmọ Yorùbá níbi àjọ̀dún náà.

Lára àwọn ètò tí wọ́n piyamọ fún ayẹyẹ Ẹ̀ṣọ́ orí lágbáyé ọ̀hún ni fífi àmì ẹ̀yẹ dá àwọn ọmọ Yorùbá àtàtà tó ti rebi-àgbànrè, bíi Ẹni tó kọ́kọ́ jẹ́ alákòóso ìjọba ẹkùn ìwọ̀-ọọ̀rùn oríléèdè Nàìjíríà, Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ẹni tó jẹ́ Ààrẹ Mùsùlùmí ilẹ̀ Yorùbá, ìpínlè Edo àti Delta nígbà ayé rẹ̀, Alhaji AbdulAzeez Aríṣekọ́lá Àlàó, àti Aláàfin àná ní ìlú Ọ̀yọ́, Ọba Làmídì Adéyẹmí kẹta, lọ́lá, fún ìmọrírì iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe nígbà ayé wọn.

Bákan náà ni ìdíje gèlè dídì yóò wáyé láàrin àwọn tó tó gbahungba sùn lọ́yẹ́, tí àwọn mẹ́ta tó bá fakọyọ jù lọ yóò sì gba ẹ̀bùn tó jọjú, àmì ẹ̀yẹ ń bẹ fún ẹni tó bá gẹ fìlà tàbí wé gèlè tó yááyì jù lọ wá síbi ayẹyẹ Ẹ̀ṣọ́ orí lágbáyé.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *