Enimere Àkànbí
Ilé aṣọ̀fin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti gbé ìgbésẹ̀ akin láti dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn tó ń fi alùpùpù àti kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹmẹ́ta kó èrò ní ìpínlẹ̀ yìí, lẹ́yìn tí aṣọ̀fin tó ń ṣojú àwọn ará ẹkùn ìdìbò àkọ́kọ́ ìwọ-ọrùn gúúsù Ìbàdàn, Ọnarébù Yusuf Adébísí, ṣe gbé àbá tó níṣe pẹ̀lú rẹ̀ ka iwájú ilé.
Nínú ìjókòó ilé tí Adari ilé, Ọnarébù Adébọ̀ Ògúndoyin, tukọ̀ rẹ̀, ni Ọnarébù Adébísí, ti kọminú lórí bí àwọn tó ń gbé alùpùpù àti kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀mẹ́ta kalẹ̀ fún àwọn tó fi ń gbé èrò pawó, ṣe ń gbé owó àsanpadà gege lé e lórí, èyí tí Aṣojúṣọ̀fin náà ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìmúnisìn lọ́nà ìgbàlódé.
Ọnarébù Adébísí, ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ń gun alùpùpù àti kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹmẹ́ta ni wọ́n ti bọ́ sínú u páhúnpẹ́ àdéhùn tí kò bójú mu pẹ̀lú àwọn tó ń gbé e kalẹ̀ fún wọn, tí wọ́n sì ń gba owó àsanpadà díẹ̀ díẹ̀ tó ju iye tí wọ́n ra àwọn irinṣẹ́ náà, lọ́wọ́ wọn, pẹ̀lú ìjìyà tó gadabú bí wọn kò bá mú àdéhùn ṣẹ.
Aṣojúṣọ̀fin ọ̀hún wá dáàbá pé kí iléeṣẹ́ ìjọba tó ń rí sí ìgbòkègbodò ọkọ̀ àti àwọn àjọ tó fara pẹ́ ẹ láti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ètò tí ó leè mú ayérọrùn fún àwọn tó ń gun alùpùpù àti kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹmẹ́ta gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ajé, nípa ṣíṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹgbẹ́ alájẹṣẹ́kù, ilé ìfowópamọ́ ayánilówó ṣòwò, tàbí àwọn ètò ìyánilówó ìjọba láti ṣe ọ̀nà bí wọ́n yóò ṣe máa gbé kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹmẹ́ta àti alùpùpù kalẹ̀, kí wọ́n sì má a san owó lọ́nà ìrọ̀rùn díẹ díẹ.
Àbá òfin ọ̀hún tí àwọn Aṣojúṣọ̀fin akẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ́wọ́gbà, ni Ọnarébù Adébísí ti gba ẹ̀ka Aláṣẹ níyànjú láti ṣe ìwádìí nípa àwọn tó ń gba owó gege lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ń gbé kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀mẹ́ta àti alùpùpù fún, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, kí wọ́n sì ṣe àgbékalẹ̀ ìgbéléwọ̀n rẹ̀, láti má a ṣe atọ́nà tó yẹ àti àkóyawọ́ nínú àdéhùn tí wọ́n bá ń ṣe.
Nígbà tí wọ́n ń fi ìwòye hàn, àwọn Aṣojúṣọ̀fin, tẹnu mọ́ ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ má a dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn tó ń fi alùpùpù àti kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀mẹ́ta gígùn ṣe iṣẹ́ ṣe, nítorí ipa tí wọ́n ń kó nínú ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti bí wọ́n ṣe ń mú ìgbòkègbodò ọkọ̀ rọrùn, pàápàá jù lọ làwọn ìgboro ìlú.
Nínù ìkáàdí ọ̀rọ̀ Adarí ilè aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọnarébù Adébọ̀ Ògúndoyin, gbóríyìn fún Ọnarébù Adébísí, fún bó ṣe gbé àbá ọ̀hún wá sí iwájú ilé, ní àkókò tó yẹ, ó sì kéde àgbékalẹ̀ àkànṣe ìgbìmọ̀ tí Aṣòfin tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò ìwọ̀-oòrùn Ọ̀yọ àti ìlà-oòrùn Ọ̀yọ́, Rahman Ọlọ́runpọ̀tó, léwájú wọn, láti ṣe iṣẹ́ lórí àbá náà.
Ọnarébù Adébísí Dáàbá Àgbékalẹ̀ Ìlànà Fáwọn Tó Ń Gbé Alùpùpù, Kẹ̀kẹ́ Ẹlẹ́sẹ̀mẹ́ta Fáwọn Sán DíẹDíẹ









Leave a Reply