SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎3SC Sá Kíjokíjo Nílùú Ìbàdàn Níwájú Bayelsa United, Tó Wá Fogun Jà Wọ́n Nínú Ìfigagbága Àkọ́kọ́ NPFL

1756058028966

Enimere Àkànbí
‎Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Shooting Stars Sports Club, 3SC ilẹ̀ Ìbàdàn bá ìjákulẹ̀ pàdé nínú ìfigagbága tí wọ́n fi ṣíde sáà 2025/2026 líìgì oríléèdè Nàìjíríà, NPFL.

‎Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Bayelsa United, ló wá kan 3SC lábùkù lójú àwọn olólùfẹ́, alátìlẹyìn àti alákóso wọn pẹ̀lú àmì ayò kan sí òfo, ní pápá ìṣerédárayá Lékan Sàlámì, ní ìlú Ìbàdàn.

‎Ìfigagbága náà ló jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí Nurudeen Awẹ́roro, yóó má a tukọ̀ 3SC, nínú líìgì oríléèdè Nàìjíríà, láti ìgbà tí ó ti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ náà, lábẹ́ ìṣàkóso Ọnọrábù Táíwò Lékan-Sàlámì.

‎Àwọn ojú tuntun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ darapọ̀ mọ́ 3SC ni ó pọ̀jù nínú àwọn agbábọ́ọ̀lù tí akọ́nimọ̀ọ́gbá, Awẹ́roro, tó tukọ̀ Ìkòròdú City ní sáà tó kọjá, kó sí orí i pápá, kojú u Bayelsa United.

‎Bí ìfigagbága ọ̀hún ṣe wọ ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ni Lawal Kẹ́hìndé, mi àwọ̀n fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Bayelsa United, tí Ṣútìn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣe máa ń pèé, kò sì leè ta pútú.

‎Ní báyìí, Ọgbọ̀njọ́ oṣù yìí, ni 3SC yóó rìnrìn àjò lọ sí ìpínlẹ̀ Edo, láti kọjú Bendel Insurance tí òhun náà pàdánù sí ọwọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù El-Kanemi Warriors, nígbà tí Bayelsa United, yóò gba Barau tó ta ọ̀mì pẹ̀lú u Enyimba, lálejò ní Ọjọ́kọkànlélọ́gbọ̀n.


‎3SC Sá Kíjokíjo Nílùú Ìbàdàn Níwájú Bayelsa United, Tó Wá Fogun Jà Wọ́n Ní Ìfigagbága Àkọ́kọ́ NPFL

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *