SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ọmọ Nàìjíríà Kan Kú Sínú Ọkọ̀ Báàlù Tó Ń Bọ̀ Láti Istanbul

img 20260428 wa0007

Enimere Àkànbí

Ẹnì kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Alhaji Isiaq Dáhùnsi, ti gbé ẹ̀mí mì nínú ọkọ̀ bàálù tó ń bọ̀ wá sí ìlú Èkó láti ìlú Istanbul, lórílẹ̀èdè Turkiye.

Àfẹ̀mọ́jú ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù keje, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, ni ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún wáyé.

Ọ̀kan lára àwọn alábàṣepọ̀ olóògbé, Ìṣọ̀lá Isiaq, tó jẹ́ Ìmáàmù ní ìjọ ẹ̀sìn Islam ti Ansarudeen, ló fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ lójú òpó ayélujára.

Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀hún sọ pé Dáhùnsi, gbé ẹ̀mí mì lákòókò tí báàlù rẹ̀ ń padà bọ̀ láti oríléèdè Türkiye, wá sí pápákọ̀ òfurufú àgbáyé Murtala Muhammed.

Ó sì bẹ Ọlọ́run Ọba Allah láti ṣe ìdáríjì fún àwọn àṣìṣe Olóògbé, kò sì gbà á sí Aljanah onídẹ̀ra.

Ohun tó ṣe okùnfà ikú Alhaji Dáhùnsi, ni Isiaq, kò sọ nínú ohun tó kọ sójú òpó ayélujára.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *