SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ọwọ́ Ba Tọkọtaya Tó Lu Ọmọ Pa Nílùú Èkó

couple kill a child

Enimere Àkànbí
Àánú Abiyamọ ṣe àwọn tó gbọ́ nípa bí tọkọtaya Paul Onyeama àti Adline Ogbonna, ṣe ṣekúpa ọmọdébìnrin ọdún mẹ́wàá, tí wọ́n gbà tọ́, ní agbègbè Ìgandò, nípìnlẹ́ Èkó.

Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe jẹ́ kó di mímọ̀ fún àwọn oníròyìn, ọjọ́ àìkú ni ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún wáyé, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀ tí wọ́n ti ń fi ọwọ́ gbígbóná mú ọmọdébìnrin náà.

Àbọ̀ ìròyìn gbé e pé tọkọtaya ọ̀hún tí wọ́n ń gbé ní àdúgbò Jemesi Papa, ti má a ń lo ọmọdébìnrin ọ̀hún nílòkulò, lùú nílùkulù, kó dá wọ́n ma ń rán ní iṣẹ́ dé tòrutòru, láì náání ọjọ́ orí rẹ̀.

Ọmọdébìnrin ọ̀hún tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Faith, ni wọ́n sọ pé ó wà lórí ìdùbùúlẹ̀ àìsàn fún bíi ọ̀sẹ̀ méjì, síbè wọ́n sọ pé tọkọtaya náà kò dẹ́kun fífi ojú rẹ̀ han èèmọ̀.

Wọ́n ní tọkọtaya ọ̀hún padà gbé ọmọdébìnrin náà dìgbà dìgbà lọ sí ilé ilé ìwòsàn, níbi tí wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wọn pé ọmọdébìnrin ọ̀hún ti gbé ẹ̀mí mì kí wọ́n tó gbé e dé.

Èyí ló mú inú bí àwọn ọ̀dọ́ agbègbè náà tí wọ́n fi mú Arábìnrin Adline Ogbonna.

Ọ̀kan lára àwọn ará agbègbè ọ̀hún, tí kò dárúkọ ara rẹ̀, sọ fún àwọn oníròyìn pé ọwọ́ àwọn ọ̀dọ́ padà ba ọkọ-ìyàwó, Paul Onyeama, tó ti tètè wá kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀mẹ́ta lọ láti fi gbé òkú ọmọdébìnrin ọ̀hún sọnù.

“Bí ọmọdébìnrin náà ṣe kú, ni wọ́n gbé òkú rẹ̀ pamọ́ sínú ilé, tí wọ́n sì ṣe bí ẹni pé ohunkóhun kò ṣẹlẹ̀, kódà ìyàwó jáde wá ní àárọ̀ yìí láti dáná ní yàrá ìdáná bíi ẹni pé nǹkan kò ṣẹlẹ̀”

Olùgbé kan, tó pe orúkọ ara rẹ̀ ní Adékúnlé Taofeek, fi tó àwọn akọ̀ròyìn létí pé, ọ̀rọ̀ di yánpọnyánrin ní ọjọ́ àìkú, nígbà tí wọ́n sọ pé ọwọ́ gbígbóná tí tọkọtaya ọ̀hún fi mú ọmọdébìnrin náà tí òjòjò fi ṣògún rẹ̀ ti padà gba ẹ̀mí rẹ̀.

Ó sàlàyé pé, “tọkọtaya ọ̀hún gba ọmọdébìnrin ọdún mẹwàá na sọ̀dọ́ ni. Tí wọ́n sì ń lòó nílòkulò pẹ̀lú ìfìyajẹ, tí wọ́n sì tún má ń rán-an ní àwọn iṣẹ́ tí kò yẹ.

Wọ́n sọ fún mi pé ọmọdébìnrin náà ti ń ṣe àìsàn láti bíi ọ̀sẹ̀ méjì, síbẹ̀ wọn kò dá ọwọ́ ìlòkulọ̀ ọ̀hún dúró. Wọ́n tún sọ pé lánàá ni tọkọtaya náà tún lu ọmọ ọ̀hún bíi kúkú bíi yíyè, láì náání ipò tí ìlera rẹ̀ wà, ó ṣe ni láànú, ọmọdébìnrin náà padà kú”
Sẹ́gun Adélakùn

 

 

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *