SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Àwọn Ẹbu Ìfọpo NNPC Kò Leè Ṣe Iṣẹ́ – Ọbásanjọ́

olusegun obasanjo nigeria president

Enimere Àkànbí

Bí Iléeṣẹ́ tó ń ṣe ìsàkóso epo bẹntirọ́ọ̀lù lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, ti tẹ̀síwájú láti má a wá àwọn alábàṣepọ̀ tó jẹ́ amojú-ẹ̀rọ, tí yóò má a tukọ̀ àwọn ẹbu ìfọpo tó ń bẹ nílùú Port Harcourt, Warri, àti Kaduna, Ààrẹ nígbà kan rí lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, tún ti sọ̀rọ̀ pé àwọn ibùdó ọ̀hún kò leè ṣe iṣẹ́

Ọbásanjọ́ sọ̀rọ̀ yìí lákòókò tó ń kópa lórí ètò iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán kan, tí ó ti ń dáhùn àwọn ìbéèrè lọ́kàn-ò-jọ̀ kan, ó sì ṣàlàyé nípa bí ìgbìyànjú ìṣàkóso rẹ̀ ṣe gbìyànjú láti fa iléeṣẹ́ Shell lójú mọ́ra, láti wá má a ṣe àmójútó àwọn ẹbu ìfọpo ọ̀hún, ṣùgbọ́n tí kò bọ́ sìi.

“Wò, nígbà tí mo wà nípò, mo pe Shell, mo ní, Ẹ dákun, Ẹ wá gba ìpín mẹ́wàá nínú ìdókòwò, kí ẹ sì má a ṣe ìṣàkóso rẹ̀. Wọ́n sọ pé rárá.

Ààrẹ nígbà kan rí náà tún ṣàlàyé nípa bí ó ṣe pé ọ̀kan lára àwọn lọ́gàlọ́gàá ní iléeṣẹ́ Shell, fún ìjíròrò ojúkojú, láti mọ ìdí tí wọ́n fi kẹ́yìn sí ohun tí òun fi lọ̀ wọ́n.

Ó sọ pé wọ́n ń ṣe ìṣàkóso ìgbésẹ̀ wíwa epo rọ̀bì jáde àti àwọn nǹkan tó rọ̀ mọ́ ọ, láì pàdánù, ṣùgbọ́n wọn kò rí èrè púpọ̀ níbẹ̀, ó jẹ́ iṣẹ́ ìsìn ju rírí èrè lọ, nǹkan àkọ́kọ́ nù u.

Bàbá Ọbásanjọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe ma ń pèé, rántí bí ó ṣe ṣàpèjúwe oríléèdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bíi èyí tí orí rẹ̀ sọre, nígbà tí Ààrẹ iléeṣẹ́ Dangote, Aliko Dangote, sọ pé òun ti ṣe tán láti fi ẹ̀ẹ̀dẹ́gbẹ̀rin-lé-ààdọ́ta mílíọ̀nù Dollar, ra ìpín mọ́kàndínlàádọ́ta nínú méjì lára àwọn ẹbu ìfọpo oríléèdè Nàìjíríà.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *