Enimere Àkànbí
Ààrẹ Bọlá Tinúbú, ti bèrè fún ìbuwọ́lu ilé aṣòfin àgbà oríléèdè lórí mílíọ̀nù lọ́nà okòólé-ní-ẹ̀ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta-dín-mẹ́rin dollar, (516 million Dollar) tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ yá lọ́wọ́ ilé ìfowópamọ́ oríléèdè Germany, láti fi ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ojú ọ̀nà.
Ẹ̀bẹ̀ ọ̀hún, ló wà nínú ìwé tí Ààrẹ ilé aṣòfin Godswill Akpabio, fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó ti ọ̀dọ̀ Ààrẹ Tinúbú wá, tó sì kàá sí etí ìgbọ́ gbogbo ilé nínú ìjókòó wọn.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé ọ̀hún, owó tí Ààrẹ Tinúbú fẹ́ yá ni ìrètí wà pé wọn yóò ló fún ìdá àkọ́kọ́, ojú kínní-kejì àkànṣe iṣẹ́ ojú ọ̀nà máṣọsẹ̀ Sokoto sí Badagry, àkànṣe iṣẹ́ tí àpapọ̀ gígùn rẹ̀ ń lọ bíi ẹgbẹ̀rún kan kìlómítà, tí abala tí iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ lórí rẹ̀ jẹ́ kìlómítà lọ́nà ọgọ́fà.
Ààrẹ Tinúbú, gba ilé aṣòfin àgbà níyànjú láti tètè gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lórí ìbéèrè òun.
Lẹ́yìn tó ka ìwé ọ̀hún tán, Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Akpabio, tari rẹ̀ sí ìgbìmọ̀ tẹ̀kótó ilé aṣòfin tó ń rí sí gbèsè oríléèdè Nàìjíríà ní abẹ́lé àti nílẹ̀ òkèèrè, fún ìgbésẹ̀ òfin lórí rẹ̀.
Gbogbo ilé sì pẹnupọ̀ pàṣẹ fún àwọn ìgbìmọ̀ náà láti mú ààbọ̀ wàá ní ọ̀sẹ̀ kan sí àkókò yìí.











Leave a Reply