Enimere Àkànbí
Àjọ elétò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, (OYSIEC), ti kéde pé ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kínní, ọdún 2027, ni ètò ìdìbò láti yan àwọn alákòóso ìjọba ìbílẹ̀, yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, wọ́n sì ṣèlérí fún àwọn olùgbé ìpínlẹ Ọ̀yọ́ pé àwọn yóò ri dájú pé ètò ìdìbò ọ̀hún lọ ní àlàáfíà pẹ̀lú àkóyawọ́.

Èyí jẹ́ ara àfẹnukò tó wáyé níbi ìpàdé àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí àwọn aṣáájú Àjọ OYSIEC ṣe pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìṣàkóso Àjọ náà, ní olú iléeṣẹ́ Àjọ OYSIEC, tó ń bẹ ní agbègbè Agodi, ní ìlú Ìbàdàn, tí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ìpàdé àkọ́kọ́ ọ̀hún tí alága Àjọ OYSIEC, Ọ̀mọ̀wé Babátúndé Afeez Adéníyì, tukọ̀ rẹ̀, fún gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ní àǹfààní láti fi orí korí, fi ikùn lukùn lórí bí Àjọ náà yóò ṣe ṣe àṣeyọrí nínú ojúṣe rẹ̀, láti ara sí ṣe ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ọ̀hún kó lọ ní àlàáfíà, kò sì jẹ́ àtẹ́wọ́gbà.
Nínú àtẹ̀jáde tí alága Àjọ OYSIEC ọ̀hún fi léde lẹ́yìn ìpàdé yìí, ni wọ́n ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé gbogbo àwọn ibùdó ìdìbò tó ń bẹ ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni ètò ìdìbò náà yóò ti wáyé láàrin aago méjọ òwúrọ̀ sí aago mẹ́ta ọ̀sán.
Wọ́n tún jẹ́ kó di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde náà pé, ìpolongo ìbò fún ètò ìdìbò ọ̀hún yóò wá sópin ní òru ọjọ́ kẹrìnlá sí ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kínní, ọdún 2027, pẹ̀lú àfikún pé àtúndì ìbò yóò wáyé ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kínní, ọdún 2027, bí ìdí bá wà láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Àjọ OYSIEC sì gba gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn níyànjú láti ṣe àtìlẹyìn àti ìfọwọ́sọwọ́pọ̀ tó yẹ fún Àjọ náà láti ṣe ètò ìdìbò ọ̀hún kó mányánlórí, láì ṣègbè lẹ́yìn ẹnikẹ́ni, pẹ̀lú ìlànà àkóyawọ́, lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù kínní, ọdún 2027.












Leave a Reply