Enimere Àkànbí
Akójánu ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Aṣòfin Gbénga Oyèkọ́lá, ti fa ojú ro sí ìwà dída erùpẹ̀, òkúta-yọyọ, bíríkì tàbí àwọn èròjà ìkọ́lé mìíràn, sí àwọn ojú òpópónà.
Aṣòfin Oyèkọ́lá, tó ń ṣe ojú ẹkùn ìdìbò Àtìbà, ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìwà àìbìkítà nípa àwọn ewu tí ó leè ti ẹ̀yìn-in rẹ̀ ṣú yọ fún àwọn ará àdúgbò tàbí àwọn tó ń rin ọ̀nà ọ̀hún kọjá, ó sì pè fún kí òpin dé bá a ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Nígbà tí Aṣòfin Oyèkọ́lá, ń pe àkíyèsí àwọn aṣojúṣòfin akẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ yìí nínú ìjókòó ilé, tí igbákejì adarí ilé, Aṣòfin Abíọ́dún Fádèyì, tukọ̀ rẹ̀, ó ṣe àlàyé kíkún nípa àwọn ewu tó rọ̀ mọ́ dída àwọn nǹkan ìkọ́lé sí ojú pópó.

Aṣòfin náà tó jẹ́ akójánu ilé, ṣàlàyé síwájú pé, ìwà yìí tó ti di bárakú lára àwọn awakọ̀ akóyọyọ, tí àwọn olùkọ́lé, tó jẹ́ oníbárà wọn náà sì ti ń faramọ́, ti ṣe okùnfà onírúurú ìjàmbá, pàápàá jù lọ, fún àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ẹ tatapùpù, nígbà tí wọ́n bá kàn àwọn nǹkan ìkọ́lé ní òjìji, ní ọwọ́ alẹ́ tàbí àfẹ̀mọ́jú.
Ní ìtẹ̀síwájú ọ̀rọ̀ Aṣòfin Oyèkọ́lá, ó tún tọ́ka sí i pé, ìwà dída erùpẹ̀, òkúta-yọyọ, bíríkì tàbí àwọn èròjà ìkọ́lé mìíràn, sí àwọn ojú òpópónà, tún ń kó ànàtúnnà owó, bá ìjọba, pẹ̀lú bí àwọn èròjà ọ̀hún, ṣe má ń padà fánká sí ojú òpópó tàbí kí wọ́n dí àwọn ojúsàn omi, nígbà tí òjò bá rọ̀, tí ó sì ma ń sọ àwọn àkànṣe iṣẹ́ ojú ọ̀nà tí ìjọba ti ṣe, di akúrẹtẹ̀.
Bákan náà, ló sọ pé, kíkó àwọn èròjà ìkọ́lé sí àwọn ojú pópó, ma ń sọ àwọn ọ̀nà di tóóró, tí àwọn ọkọ̀ yóò sì ní láti má a súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ní ojú òpópónà kí wọ́n tó rí ààyè kọjá.
Aṣòfin Oyèkọ́lá, wá dá àbá pé kí ẹ̀ka aláṣẹ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, bẹ̀rẹ̀ sí ní fi imú ẹnikẹ́ni tó bá da èròjà ìkọ́lé rẹ̀ sí ojú pópó, tí kò sì ṣe àmúlò rẹ̀, ní ààrin wákàtí máàrún, fín ata òfin.
Akójánu ilé ọ̀hún fikùn-un pé kí ẹ̀ka ilé’ṣẹ́ ìjọba tó ń rí sí àmójútó àyíká àti àlùmọ́ọ́nì inú omi, gbé òfin kalẹ̀ pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ fi erùpẹ̀, òkúta-yọyọ, bíríkì tàbí àwọn èròjà ìkọ́lé mìíràn, sílẹ̀ ní àwọn ojú òpópónà, di alẹ́, kí ìjìyà tó gbópan sì tó ẹnikẹ́ni tó bá tàpá síi, lọ́wọ́.
Bákan náà ló ń fẹ́ kí àwọn àjọ tó ń ṣe àmójútó àwọn ojú òpópónà, bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ọwọ́ tó le mú àwọn tí kò bìkítà nípa àwọn ohun tí wọ́n ń kó sí àwọn ojú òpópónà.











Leave a Reply