Enimere Àkànbí
Àṣálẹ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun ni àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ìjọ Àpọ́sítélì ti Kírísítì, CAC, ní agbègbè Ẹ̀dá Oníyọ̀-Èkìtì, ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìlejèméje, ìpínlẹ̀ Èkìtì, wọ́n ṣe ikú pa olùṣọ́-àgùntàn, wọ́n sì tún kó àwọn olùjọ́sìn tí kò níye lọ.
Ìkọlù ọ̀hún tó wáyé, ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ ààbọ̀ àṣálẹ́ tí ìsìn ń lọ lọ́wọ́, ló kó ìbẹ̀rù bojo bá àwọn ará agbègbè náà, nípa ipò tí ààbò ẹ̀mí àti dúkìá wọ́n wà.
Àwọn ará agbègbè ọ̀hún ṣàlàyé pé àwọn tó ṣe ìkọlù náà pọ̀ níye, pẹ̀lú ìhámọ́ra, tí wọ́n sì ya bo ilé ìjọsìn náà tó wà ní etí ìlú, wọ́n yìnbọn pa òjíṣẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì jí àwọn ọmọ ìjọ lọ sínú igbó ńlá tó wà nítòsí.
Ọ̀kan lára àwọn tó bá ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ kí orúkọ rẹ̀ jáde nínú ìròyìn, ṣàlàyé pé ìgbìyànjú ń lọ lọ́wọ́ láti mọ iye èèyàn tí wọ́n jí gbé lọ.
Nígbà tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nípìnlẹ́ Èkìtì, ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀, wọ́n jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn ti rán ikọ̀ aláàbò jáde láti lọ ṣe àwárí àwọn tí wọ́n mú sí ìgbèkùn, kí wọ́n sì gbà wọ́n sílẹ̀.
Sẹ́gun Adélakùn











Leave a Reply