Enimere Àkànbí
Ẹni tó ń léwájú láti jẹ́ olùdíje dupò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic, PDP, Àjàdí Ògúntóyìnbó, ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìpadà sí ilé ẹ̀kọ́, ní ẹkùn Ìbàdàn.
Níbi ètò ọ̀hún tó wáyé lọ́jọ́ ìṣẹ́gun, ni wọ́n ti pín aṣọ ilé ẹ̀kọ́, ìbọsẹ̀, bàtà àti àwọn èròjà ìkẹ́kọ̀ọ́ míì, fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí owó ń tá àwọn òbí wọn lọ́wọ́.
Lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ṣe ètò náà ni ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ Òde Ajé, ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ kìnní-kejì St. Brendan, tó ń bẹ ní agbègbè Kúmápàyí, ní Olódó, ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ ID, Odò-ọnà, ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ HL. A Special School, tó ń bẹ ní agbègbè Gate àti ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ St. Luke’s Demonstration Basic School, Mọ̀lété, Ìbàdàn, ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ St. John, tó ń bẹ ní Erùnmu.

Ẹ ó rántí pé Àjàdí, sọ pé bí àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bá leè fi ìbò gbé òun wọlé ní ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, òun yóò mójútó àwọn ẹ̀bùn tó ń bẹ ní ẹsẹ̀kùkú, bákan náà ni òun yóò pèsè àtìlẹyìn fún àwọn ọmọ aláìní.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, àfojúsùn ètò ọ̀hún tí yóò wáyé ní ẹkùn gbogbo tó ń bẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni láti ṣe àtìlẹyìn àti ìpèsè àwọn èròjà ìkẹ̀kọ̀ọ́, fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kò rí ọwọ́ họrí, tí àpapọ̀ wọn jẹ́ igba níye, lójúnà láti mú àdínkù bá iye àwọn ọmọ tó ti pa ẹ̀kọ́ tì nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́.
Ó ṣàlàyé síwájú pé ètò ọ̀hún tí òun àti Àjọ Catch Them Young Campaign, jùmọ̀ ṣe àgbékalẹ̀, ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lé ní ọ̀ọ̀dúnrún níye ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba káàkiri ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti jẹ àǹfààní rẹ̀.
Díẹ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ àǹfààní ètò náà, gbóríyìn fún Àjàdí tó ń gbèrò láti di Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, fún bó ṣe pẹ̀ka mùkúndùn ìjọba àwarawa dé ọ̀dọ̀ wọn ní ẹsẹ̀kùkú, èyí tí wọ́n ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ipa ọjọ́ ọ̀la tó dára tí kò leè parẹ́ láíláí.
Bákan náà ni díẹ̀ lára àwọn Ọ̀gá olùkọ́ tí ètò ọ̀hún dé, bíi Abilékọ Victoria Ọ̀pádọ̀tun, ti ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ St. Luke’s Demonstration Basic School, Mọ̀lété, Ìbàdàn àti Abilékọ Cecilia Akínpẹ̀lú, ṣàlàyé nípa àwọn ìṣòro tó ń bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fínra.
Wọ́n jẹ́ kó di mímọ̀ pé ètò ọ̀hún yóò la ipa rere lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn jẹ́ ọmọ òrukàn, aláìnílélórí, àti àwọn tí wọ́n wá láti inú ẹbí tí ọkọ àti aya ti kọ ara wọn.
Àwọn àgbà olùkọ́ ọ̀hún tí wọ́n ṣàpèjúwe ètò tí Àjàdí gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìrètí ọ̀tun, fi kún un pé ètò náà yóò tún ìròrí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún ṣe, tí yóò sì mú wọn dúró ní ilé ẹ̀kọ́.
Àwọn alákòóso ètò ẹ̀kọ́ ọ̀hún sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn òbí, alágbàtọ́ àti àwọn tí elédùmarè jogún ọlá fún láwùjọ, láti ṣe ìrànwọ́ fún ètò ẹ̀kọ́ ní ìpele Alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀, káàkiri ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ẹni kan tó jẹ́ òbí àwọn ọmọ ìbejì tó ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ St. John, tó ń bẹ ní Erùnmu, dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ ẹni tó na ọwọ́ ọrẹ sí wọn, ó sì túbọ̀ fìdí àtìlẹyìn rẹ̀ múlẹ̀ fún ìṣàkóso Gómìnà Ṣèyí Mákindé, ti Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Ó gba àwọn òbí níyànjú láti má a ṣe ohun tó tọ́, tó yẹ fún ètò ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n dẹ́kun ìwà àìnání nípa ìtọ́jú ọmọ àti rírè wọn fún ìwúlò ọjọ́ ọ̀la, kí wọ́n leè bá di ọmọ tí yóò ṣe é mú yangàn lọ́jọ́ iwájú.
Ṣáájú ni Ọ̀gá àgbà Àjọ “Catch Them Young Initiative Campaign” tó kún Àjàdí lọ́wọ́ ṣe àgbékalẹ̀ ètò náà, Abilékọ Ayọ̀dení Àlùkò, ṣàlàyé pé ètò ọ̀hún tó jẹ́ àgbékalẹ̀ òun, tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi ọwọ́ sí, jẹ́ àfojúsùn láti ṣe ìrànwọ́ fún ìdàgbàsókè àwọn ògo wẹrẹ láti le wúlò fún ara wọn, òbí àti àwùjọ lápapọ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Ó sì túbọ̀ pé fún ìkún lọ́wọ́ àti àtìlẹyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn tí elédùmarè dá lọ́lá, kí ètò ọ̀hún le ba à dé ibi gbogbo ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Bẹ́ẹ̀ ètò yìí ni Àjàdí ṣèlérí láti pẹ̀ka dé àwọn ẹkùn yòókù tó ń bẹ nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, láàrin ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sí àkókò yìí.











Leave a Reply