SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

WỌ́N YÌNBỌ PA ONÍṢÒWÒ SHAWARMA NÍLÙÚ ÈKÓ

images

Enimere Àkànbí
Àwọn kan tí wọ́n fura sí gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn, ti yin ìbọn pa ẹnì kan tó jẹ́ oníṣòwò nǹkan ìpanu kan, Shawarma, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Andy, ní agbègbè Ṣàngótẹ̀dó, nípìnlẹ́ Èkó.

Àṣálẹ́ ọjọ́ àbámẹ́ta ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé.

Ìwádìí fi yé ni pé, lákòókò tí Andy, ń dá àwọn oníbàárà rẹ̀ lóhùn lọ́wọ́ ni àwọn kan tó da nǹkan bójú ṣàdédé dé síbẹ̀, tí wọ́n sì sùn mọ́-ọn dáadáa, kí wọ́n tó ròjò ìbọn fún-un.

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ pé ojú ẹsẹ̀ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn tán ni wọ́n na pápá bora, tí wọ́n sì fi Andy sílẹ̀ nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀.

Ọlópàá tó ń tọpinpin ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún, sọ fún àwọn oníròyìn pé àwọn onítọ̀hún ṣe bí i oníbàárà wá bá Andy, láti wọlé síi lára, kó tó di pé wọ́n kọlùú.

Ó fi kún-un pé nígbà tí àwọn ọlọ́pàá yóò fi dé ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ ti wáyé, àwọn oníṣẹ́ láabi ọ̀hún ti fi ẹsẹ̀ fẹ́ẹ, tí àwọn sì gbé òkú rẹ̀ kúrò.

Ọlọ́pàá náà sọ pé, títí tí ìwádìí yóò fi parí, ẹnikẹ́ni kò tíì leè lọ́ ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà mọ́ àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn.
Sẹ́gun Adélakùn

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *