SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Agbébọn Gba Ẹ̀mí Aṣáájú Ẹ̀sìn Ní Adamawa

images (8)

Enimere Àkànbí
Ikọ̀ agbébọn ti ṣe ikú pa òjíṣẹ́ Ọlọ́run, Emmanuel Ezeoikwe, ní abúlé Zinal, ní ìjọba ìbílẹ̀ Song, ní ìpínlẹ̀ Adamawa.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní òwúrọ̀ ọjọ́ ìṣẹ́gun, ní ilégbèé olóògbé.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Adamawa, Suleiman Nguroje, tó fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde, ṣàlàyé pé aago mẹ́fà ààbọ̀ òwúrọ̀, ni wọ́n fi tó àwọn létí pé ní aago kan òru ọjọ́ ìṣẹ́gun, ni àwọn agbébọn ọ̀hún kọ lu abúlé náà, tí wọ́n sì yin ìbọn pa olóògbé.

Ó ní lọ́gba tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí dé etígbọ̀ọ́ àwọn, ni àwọn ọlọ́pàá yára gbéra lọ sí ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ti wáyé, tí wọ́n sì bá olóògbé níbi tó sùn bọrọgidi sí, síbẹ̀ àwọn sáré gbé e dìgbà dìgbà lọ ilé ìwòsàn, níbi tí wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ó ti gbé ẹ̀mí mì.

Wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí ilé ìgbé òkú pa mọ́ sì, fún àyẹ̀wò tí wọn yóò fi mọ irú ikú tó pa á.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ọ̀hún jẹ́ kó di mímọ̀ pé òfìfo ilé ọta ìbọn mẹ́ta ni àwọn rí níbi tí ìkọlù tí wáyé.

Nguroje, tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní pẹrẹ hu nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣe ikú pa ni náà.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, Ọ̀gá ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Adamawaw Kabir Hassan, ti pàṣẹ pé kí ọ̀rínkínniwín ìwádìí bẹ̀rẹ̀, kí àwọn sì kó àwọn ikọ̀ tó ń fi ọgbọ́n àtinúdá pèsè ààbò síta láti tọ ipàsẹ́ àwọn oníṣẹ́ ibi ọ̀hún.

Ó gba èrò àwùjọ níyànjú láti má ṣe mikàn, ṣùgbọ́n kí wọ́n ríi dájú pé wọn kò fi ohunkóhun tí àwọn agbófinró nílò fò wọ́n ru, ní bí iṣẹ́ ìwádìí ṣe ń lọ lọ́wọ́.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *