SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎Àwa La Fún Yín Nílẹ̀, Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Dá Ìjọba Àpapọ̀ Lóhùn

IMG 20251023 WA0130

Enimere Àkànbí
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí fún ìjọba àpapọ̀ oríléèdè Nàìjíríà lésì ọ̀rọ̀ ìfitónilétí tó gbéjáde lọ́jọ́ kejìlélógún oṣù yìí, ní ojú ìwé méjìlélógún ìwé ìròyìn Tribune, pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe ta àwọn nǹkan ìní tàbí ilẹ̀ tí òun ní sí ọ̀nà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

‎Alákòóso fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀, ilégbèé àti ìdàgbàsókè àwọn ìgboro ìlú ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Williams Akin-Fúnmiláyọ̀, ló gba ẹnu ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fèsì, níbi ìpàdé oníròyìn tó wáyé ní iléeṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ọ̀hún, tó ń bẹ nínú ọgbà Secretariat, Ìbàdàn.

‎Ọ̀gbẹ́ni Akin-Fúnmiláyọ̀, ṣàlàyé pé yàtọ̀ sí pé àgbékalẹ̀ ìwé òfin ilẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ gbékalẹ̀ lọ́dún-un 1978 fún àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ ní agbára gẹ́gẹ́ bíi onilẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló fún ìjọba àpapọ̀ ní àwọn ilẹ̀ ọ̀hún làwọn àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, pẹ̀lú àfẹnukò pé wọn yóò ló wọ́n fún àwọn nǹkan tí wọ́n bèèrè àwọn ilẹ̀ náà fún.

‎Ọ̀gbẹ́ni Akin-Fúnmiláyọ̀, sọ pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilẹ̀ ọ̀hún ni ìjọba àpapọ̀ kò lò fún àwọn nǹkan tí wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ lò wọ́n fún, wọ́n lo kékeré nínú àwọn míràn, wón sì lo àwọn kan ní àlòpatì èyí tó leè jẹ́ kí àwọn agbègbè náà di ibùba àwọn oníṣẹ́láabí.

‎Alákòóso iléeṣẹ́ ìjọba ọ̀hún fikùn pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ẹ̀tọ́ láti gba àwọn ilẹ̀ náà padà fún ìdàgbàsókè ìlú àti ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, bí ìjọba àpapọ̀ kò bá lò àwọn ilẹ̀ ọ̀hún láàrin àkókò kan sí àkókò míràn.

‎Ní Itesiwaju ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Akin-Fúnmiláyọ̀, ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn ti gba àwọn kan padà lára àwọn ilẹ̀ náà, tí àwọn kó sì sún mọ́ règbèrégbè àwọn ilẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ ń ló bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, pápá jùlọ, ilẹ̀ tó ń bẹ ní agbègbè Ìdí-Ayùnrẹ́.

‎Ṣáájú ni ìjọ́ba àpapọ̀ nínú ìwé ìròyìn ọ̀hún ṣe ìkìlọ̀ pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe sún mọ́ ibi nǹkan ìní òun wà tàbí ta ilẹ̀ òun tó ń bẹ ní ibùdó ìpèsè nǹkan ní ẹkùn ilẹ̀ adúláwọ̀ African Regional Centre and Manufacturing (ARCEDEM) tó ń bẹ ní agbègbè Wọ̀fún-Olódó, Ìbàdàn, Ètò Ilégbèé Olówó Kéréje tí ìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀ (Federal Low Cost Housing Estate) Ìdí-Ayùnrẹ́, Ètò Ilégbèé tí Ìjọba àpapọ̀ gbékalẹ̀ (Federal Housing Scheme Program) tó ń bẹ ní Ṣakí, Ibùdó tí wọ́n ń ṣe àwọn erè oko oní kóró lọ́jọ̀ sí(National Strategic Grain Reserve Program) tó ń bẹ ní agbègbè Ìyànà-Church, Mọ́nàtán, ilẹ̀ tó jẹ́ nǹkan ìní iléeṣẹ́ Radio Nigeria, tó ń bẹ ní agbègbè Baṣọ̀run, Ìbàdàn àti Ibùdó iṣẹ́ ìwádìí nípa ọ̀gbìn èso àti òdòdó (National Horticultural Research Institute, Alẹ́ṣinlọ́yẹ́, Ìbàdàn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *