SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎Gómìnà Mákindé Ń Dá Owó Jọ Fún Ọjọ́ Ọ̀la Ọrọ̀-Ajé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

IMG 20251018 WA0001

Enimere Àkànbí
‎Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ, Ṣèyí Mákindé, ti ṣàlàyé pé ìṣàkóso òun gbìyànjú láti fi owó tó tó ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù dollar pamọ́ sínú àpò àsùnwọ̀n èrè orí ìdókòwò, fún ọjọ́ ọ̀la ọrọ̀-ajé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ìrọ̀rùn àwọn ará ìlú.
‎
‎Gómìnà Mákindé, jẹ́ kó di mímọ̀ bẹ́ẹ̀ níbi ìpàdé oníròyìn tó dá lórí í àbájáde ìfilọ́lẹ̀ ètò Ibùdó ajé àtètò ìdokowo tí kò lowo orí nínú láàrin àwọn oríléèdè ilẹ̀ adúláwọ̀ (AfCFTA), tó wáyé nínú ọgbà Secretariat, Ìbàdàn.
‎
‎Gómìnà ṣàlàyé pé owó ọ̀hún tí yóó ran ìfìdìímúlẹ̀ àgbékalẹ̀ ètò (AfCFTA) àti àwọn ètò ọrọ̀ ajé ọlọ́jọ́ pípẹ̀ mìíràn lọ́wọ́, ni òun ti rí bíi mílíọ̀nù mẹ́fà lé díẹ̀ dollar kójọ níbẹ̀ pẹ̀lú àfojúsùn láti wá kún-un kí ìṣàkóso òun tó tẹnu bodò lọ́dún 2027.
‎
‎Bákan náà ló jẹ́ kó di mímọ̀ pé yàtọ̀ sí èrè ọlọ́jọ́ pípẹ́, àwọn àgbẹ̀ aládàá kékeré àti àwọn olokowo kéékèèké le è ní àǹfààní sí ojú òpó ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti ṣe ìdókòwò ní ilẹ̀ adúláwọ̀.
‎
‎Gómìnà Mákindé tún sọ pé àfojúsùn ìṣàkóso òun ni láti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ètò tí yóò bí ìṣèjọ̀ba rere àti ìdàgbàsókè ọlọ́jọ́ pípẹ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
‎
‎Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ olùdámọ̀ràn Gómìnà Mákindé lórí ọ̀rọ̀ àjọ AfCFTA, Arábìnrin Neo Tlhaselo, ṣàlàyé pé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀ àkọ́kọ́ ní gbogbo ilẹ̀ adúláwọ̀, tó gbójúgbóyà buwọ́lu ìfilọ́lẹ̀ àgbékalẹ̀ ètò AfCFTA, èyí tí àwọn oríléèdè kan gan-an kò tíì rí ṣe, ti ní àǹfààní báyìí láti kópa sòòsé nínú ètò okoòwò àti ọrọ̀ ajé àgbáyé.
‎
‎
‎

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *