Enimere Àkànbí
Alága àjọ elétò ìdìbò ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, OYSIEC, Ààrẹ Isiaka Ọlágúnjú, SAN, ti gba àwọn tí ọ̀rọ̀ kán-àn nímọ̀ràn láti má a fi àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí wọ́n ní ìmọ̀, òye àti ìrírí kíkún nípa ìṣàkóso ètò ìdìbò, sí ipò ìṣàkóso ìdìbò, Ó sì tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bíi ohun tí yóó mú ìdàgbàsókè bá àbájáde àwọn ètò ìdìbò ní oríléèdè Nàìjíríà.
Níbi ayẹyẹ ìdágbére tí àwọn alákòóso àjọ OYSIEC ṣe, láti fi bu ọlá àti ẹ̀yẹ fún Àgbọ̀jẹ̀ Agbẹjórò náà, ni Ààrẹ Ọlágúnjú, ti sọ ọ̀rọ̀ ìmọ̀ràn yìí.
Ààrẹ Ọlágúnjú, ṣàpèjúwe àjọ elétò ìdìbò gẹ́gẹ́ bíi iléeṣẹ́ tó ṣe pàtàkì, tí ó yẹ kó jẹ́ wípé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, àwọn tó gba àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn tó mú ètò ìdìbò bíi ìṣe, ni wọn yóó máa gbé iṣẹ́ náà lé lọ́wọ́, kí ìmúṣẹ àfojúsùn àgbékalẹ̀ rẹ̀ le máa jọ, kí ó sì máa tẹ̀sìwájú.

Ní ìtẹ̀sìwájú ọ̀rọ̀ Agbẹjórò náà, Ó ṣàlàyé pé ìdí tó yẹ kí wọ́n fi jẹ́ kí àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ tó ń ba àjọ ọ̀hún ṣiṣẹ́, má a bá iṣẹ́ wọn lọ, láì gbé wọn lọ sí ibòmíràn, kò ṣe fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn.
“Ìfi ẹ̀bùn ṣòfò ni bí wọ́n bá gbé ọ̀ṣíṣẹ́ kan tó ti ní ìmọ̀ kíkún àti ìrírí nípa ètò ìdìbò láti OYSIEC, lọ sí iléeṣẹ́, ẹ̀ka tàbí àjọ mìíràn tó jẹ́ ti ìjọba”
Nígbà tó ń fi ẹ̀mí ìmòre hàn sí Gómìnà Ṣèyí Mákindé, fún ànfàní tí ó fún òun àti àwọn ikọ̀ tí wọ́n jọ ṣe iṣẹ́ pọ̀, láti kó ipa ti wọn náà nínú ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Alága àjọ OYSIEC ọ̀hún, gba àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ àjọ náà níyànjú láti máa ṣe fà sẹ́yìn nínú ìlàkàkà wọn láti dé ibi gíga láyé.
Nínú ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ àjọ OYSIEC, wọ́n dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ ọ Gómìnà Mákindé, fún bó ṣe kà wọ́n yẹ láti sin àwọn ará ìlú, láti ara àjọ elétò ìdìbò ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Wọ́n sì gba àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ OYSIEC nímọ̀ràn láti má ṣe yẹ ẹsẹ̀ kúrò lójú òpó iṣẹ́ rere àti ìmúratán wọn sí ojúṣe wọn, kí wọ́n ríi dájú pé wọ́n bá àwọn mìíràn tí Gómìnà bá yàn ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe bá àwọn ṣe.

Nígbà tí akọ̀wé àgbà àjọ OYSIEC, Arábìnrin Abísọ́lá Ògúnmọ́lá, náà ń sọ̀rọ̀, Ó tọ́ka sí àjọṣe pọ̀ tó gúnmọ́ láàrín àwọn ọ̀ṣíṣẹ́ àti aṣáájú àjọ ọ̀hún, gẹ́gẹ́ bí i àṣírí àṣeyọrí gbogbo tí àjọ ọ̀hún ṣe.
Ó gbóríyìn fún ìlànà aṣáájú tí Ààrẹ Ọlágúnjú àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ fi ṣe ojúṣe wọn lábẹ́ àjọ elétò ìdìbò ọ̀hún, pẹ̀lú àfikún pé “ó ran òun lọ́wọ́ nínú àṣeyọrí tí òun ṣe, Ó sì ṣe ní àdúrà pé kí Elédùmarè bùkún wọn, kó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n bá dá ọwọ́ lé lórí”
Lára àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ìṣàkóso àjọ OYSIEC tó wà níbi ayẹyẹ ìdágbére ọ̀hún tó wáyé ní olú iléeṣẹ́ àjọ náà, ni, Olóyè Kúnmi Agboọlá, Ọ̀gbẹ́ni Emmanuel Ọláńrewájú, Ọnarébù Rẹ̀mí Ayọ̀adé, Ọ̀gbẹ́ni Sunday Fálànà, Ọ̀mọ̀wé Afees Adéníyì àti Alhaja Ganiyat Sàká.
Àwọn yòókù ni, Akọ̀wé àgbà àjọ OYSIEC, Arábìnrin Abísọ́lá Ogúnmọ́lá, Adarí ètò ìṣúná, Arábìnrin Kíkẹ́lọmọ Ọlátúnjí, Adarí ìpalẹ̀mọ́ ètò ní ọ́fìsì Gómìnà, Ọ̀gbẹ́ni Kẹ́hìndé Ayọ̀dèjìm àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.

Fífi ẹ̀bùn ta ni lọ̀rẹ́, àkànṣe àdúrà àti ìránra-ẹniléti àwọn àjọṣe pọ̀, ni ara àwọn ètò tí wọ́n ṣe níbi ayẹyẹ náà.
Lábẹ́ ìṣàkóso ikọ̀ yìí tí Ààrẹ Isiaka Ọlágúnjú, jẹ́ alága wọn gẹ́gẹ́ bí Gómìnà Ṣèyí Mákindé, ṣe yàn wọ́n ní ọjọ́ kẹta, oṣù kẹsàn-án, ọdún 2022, ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ nígbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wáyé, tí àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sì jáde lọ ṣe ojúṣe wọn.











Leave a Reply