SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎Super Falcons Pajúdà Fa Atlas Lionesses Ya, Lójú Àwọn Ọmọ Morocco Láṣekágbá WAFCON

Images 4

Enimere Àkànbí
‎Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù lóbìnrin oríléèdè Nigeria, Super Falcons, fi ìyà jẹ olùgbàlejò ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ adúláwọ̀(WAFCON) ti ọdún 2024, Morocco, ní àṣekágbá pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sí méjì, láti gba ife ẹ̀yẹ náà fún ìgbà kẹwàá.

‎Nínú ìfigagbága ọ̀hún tó wáyé ní pápáṣerédárayá Olympic, Nílùú Rabat, lórílẹ̀èdè Morocco, ni èsúró ikọ̀ Super Falcons ti pajúdà sí ajá ikọ̀ Atlas Lionesses, ti oríléèdè Morocco, tó ti kọ́kọ́ ń lékè pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òfo ní abala àkọ́kọ́.

Images 1 1

‎Abala kejì ni Super Falcons ti tayọ ju alátakò wọn, Atlas Lionesses, tó já wọn ní tànmọ́ọ̀ ní ìpele tó kángun sí àṣekágbá ìdíje WAFCON ti ọdún 2022.

‎Balógun ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù lóbìnrin oríléèdè Morocco, Ghizlane Chebbak, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ló kọ́kọ́ mi àwọ̀n ní ìṣẹ́jú mẹ́tàlá tí ìfigagbága bẹ̀rẹ̀, kí Sanaa Mssoudy, tó fi ọba lé e ní ìṣẹ́jú mọ́kànlá lẹ́yìn tí àkọ́kọ́ wọlé.

‎Àmi ayò méjì sí òfo yìí ni wọ́n gbé lọ ní abala àkọ́kọ́, tí inú àwọn ọmọ oríléèdè Morocco sí ń dùn pé, àwọn yóó rí ife ẹ̀yẹ WAFCON gbà fún ìgbà àkọ́kọ́.

Gwz86JpWIAE5NkM 240x300

‎Nígbà tí ó di ìṣẹ́jú méjìdínlọ́gọ́ta lábala kejì, ni Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Super Falcons, Justin Madugu, ṣe àtúnṣe sí ààrin gbùngbùn, nípa fífi Babájídé Rìnsọ́lá àti Jennifer Echegini rọ́pò Chinwendu Ihezuo àti Halimatu Àyìndé.

‎Kò ju ìṣẹ́jú márùn-ún lọ lẹ́yìn ìgbẹ́sẹ̀ yìí, tí Super Falcons rí bọ́ọ̀lù golí wòmí kíi n gbá sáwọ̀n, nítorí agbábọ́ọ̀lù ọmọ oríléèdè Morocco, tí bóọ̀lù kán-àn ní ọwọ́, lójú ilé wọn.

‎Esther Okorownkwo, ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, sì lo àǹfààní yìí láti gbá ayò àkọ́kọ́ wọ inú àwọ̀n fún oríléèdè Nigeria, ìṣẹ́jú mọ́kàléláàdọ́rin ni Okorownkwo tún ran ẹni ọdún mẹ́rìnlèlógún, Fọláṣadé Ijamilusi, lọ́wọ́ láti jẹ ayò kejì fún Super Falcons.

Images 2 300x168

‎Lọ́gba bẹ́ẹ̀ ni ikọ̀ Morocco àti Nigeria, jọ dọ́gba pẹ̀lú àmì ayò méjì, méjì, tí onikaluku wọn sì jọ ń tiraka láti fi ẹ̀yìn ara janlẹ̀.

‎Nígbà tó di ìṣẹ́jú méjìdínlọ́gọ̀rín ni agbábọ́ọ̀lù Super Falcons, Jennifer Echegini, ẹni ọdún mẹ́rìnlèlógún, gbá bọ́ọ̀lù kẹta wọ inú àwọ̀n olùgbàlejò ìdíje, Atlas Lionesses, tó sì da nǹkan sí oríléèdè Morocco lágbada, èyí tó jẹ́ nǹkan ìdùnnú fún àwọn ọmọ oríléèdè Nigeria.

18881NM2 236x300

‎Gbogbo ìgbìyànjú àwọn agbábọ́ọ̀lù Morocco láti tún nǹkan ṣe láàrin ìṣẹ́jú péréte tó kù, ló já sí pàbó.

‎Ní ìparí ìfigagbága ọ̀hún tí ọmọ oríléèdè Namibia, tukọ̀ rẹ̀, oríléèdè Nigeria fàgbà han Morocco pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sí méjì.

Images 1 1

‎Èyí ló jẹ́ kó di ìgbà kẹwàá tí Super Falcons yóò gba ife ẹ̀yẹ WAFCON, àti ìjákulẹ̀ kejì ní sísẹ̀-n-tẹ̀ní, fún oríléèdè Morocco, tó pàdánù àṣekágbá yìí, ó wáyé bẹ́ ẹ̀ náà ní ọdún 2022 tí wọ́n fìdírẹmi sí ọwọ́ South Africa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *