Enimere Àkànbí
Ìpele àgbà-ọ̀jẹ̀ iréèje àgbàríjọpọ̀ àwọn Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù láti gba adé sáà ẹgbàá-lé-mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sí ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n lórílẹ̀èdè Nàìjíríà (NPFL) parí lọ́jọ́ àìkú, ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù karùn-ún, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, pẹ̀lú ìdùnnú, ìbànújẹ́ àti ìrírí mánigbàgbé fún onírúurú Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù.
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Enugu Rangers àti Rivers United, ló jọ du adé ọ̀hún mọ́ ara wọn lọ́wọ́, tí Enugu Rangers tó lọ sí òkè ìta, sì dùnnú bọ̀ láti ìlú Èkó tí wọ́n ti lọ kojú Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Ìkòròdú City, tó nílò ìjáwé olúborí láti peregedé fún ìdíje láàrin àwọn akọni Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ní ilẹ̀ adúláwọ̀.
Rivers United, tí ọ̀hún fi àgbà han Katsina United, pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sí òfo, parí sí ipò kejì, lẹ́yìn Rangers International, tó fi ẹ̀yìn Ìkòròdú City janlẹ̀ ní pápáṣeré ìdárayá Mobọ́lájí Johnson Arena, Oníkàn-án nípìnlẹ́ Èkó, pẹ̀lú àmì ayò kan sí méjì.

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Shooting Stars Sports Club, 3SC ilẹ̀ Ìbàdàn, ni ó jẹ àǹfààní tí Ìkòròdú City pàdánù.
Bó ti lẹ̀ jẹ́ pé 3SC náà pàdánù ìfigagbága wọn sí ọwọ́ Niger Tornadoes, pẹ̀lú àmì ayò kan dondo, tí wọ́n gbá wọ inú àwọ̀n wọn láti ara bọ́ọ̀lù aṣọ́lé wò mí kíi gbá a sáwọ̀n, síbẹ̀ wọ́n kógojá fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n sẹ́yìn fún ìdíje láàrin àwọn Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó ń bẹ ní ilẹ̀ adúláwọ̀.
Ọdún ẹgbàá-dín-kan (1999) ni Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà, tó fi pápáṣeré ìdárayá Lékan Salami, tó ń bẹ ní agbègbè Adámásingbà ní ìlú Ìbàdàn, ṣe ilé, ti kópa kẹ́yìn nínú Àjọ CAF.
Ṣáájú ìfìdírẹmi 3SC sí ọwọ́ Niger Tornadoes, tó nílò ìjáwé olúborí láti fi bọ́ kúrò lára àwọn Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí wọ́n ṣubú padà sí ìpele kejì iréèje àgbàríjọpọ̀ àwọn Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Olúyọ̀lé Warriors, fi àmì ọgọ́ta jókòó sí ipò kẹta lórí ìgbéléwọ̀n.
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà ló jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó ṣe pàtàkì ní oríléèdè Nàìjíríà àti ní ilẹ̀ adúláwọ̀, láti ara àwọn àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe láti ẹ̀yìn wà.
3SC ni Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, tó gba ìfẹ́ ẹ̀yẹ láàrin àwọn akọni Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ní ilẹ̀ adúláwọ̀, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe gba ife ẹ̀yẹ (African Cup Winners’ Cup) ní ọdún ẹgbàá-dín-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (1976)
Ní ọdún ẹgbàá-dín-mẹ́jọ(1992) wọ́n tún gba ife ẹ̀yẹ (CAF Cup), wọ́n sì tún wọ àṣekágbá ife ẹ̀yẹ (African Cup of Champions Club) lọ́dún ẹgbàá-dín-mẹ́rìndínlógún (1984) àti ọdún ẹgbàá-dín-mẹ́rin (1996), èyí tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ ara àwọn Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó ṣe àṣeyọrí jùlọ ní ilẹ̀ adúláwọ̀.

Lára àwọn nǹkan tó jẹ́ mánigbàgbé nípa ìpele àgbà-ọ̀jẹ̀ iréèje àgbàríjọpọ̀ àwọn Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù láti gba adé sáà ẹgbàá-lé-mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sí ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n lórílẹ̀èdè Nàìjíríà (NPFL) ni bí Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó gba adé ọ̀hún kẹ́yìn, Remo Stars, ṣe yọ̀ padà bọ́ sí ìpele kejì, láti ara bí wọ́n ṣe ta ọ̀mì ayò pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Bendel Insurance, nílùú Benin.
Bákan náà ni Elkanemi Warriors, tó fìdí rẹmi pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sí òfo sí ọwọ́ Enyimba, darapọ̀ mọ́ Bayelsa United àti Wikki Tourists, gẹ́gẹ́ bíi àwọn Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí yóò lọ tun kó ní ìpele kejì.












Leave a Reply